Ẹ gba mi lọwọ awọn aja APC to n halẹ mọ mi nitori mo ni mi o ṣe oṣelu o-Mista Macaroni

Jọke Amọri

Ọkan ninu awọn adẹrin-in poṣonu ilẹ wa to tun jẹ oṣere tiata to maa n gbe fiimu keekeeke ori ayelujara jade, Debọ Adedayọ ti gbogbo eeyan mọ si Mr Macaroni, ti pariwo sita pe ki gbogbo ọmọ orileede Naijiria gba oun lọwọ awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC kan ti wọn n halẹ mọ oun nitori pe oun ni oun ko ṣe oṣelu. Oṣere yii fi aidunnu rẹ han si bi awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC ṣe n dunkooko mọ ọn, ti wọn si maa n fojoojumọ bu u nitori pe ọmọkunrin naa loun ko ṣatilẹyin fun ẹgbẹ APC tabi ẹgbẹ oṣelu kankan.

Oṣere naa ni owe Yoruba kan lo sọ pe ‘ipa ko raja, ipa ko si ta a’, o ni ki i ṣe dandan ko jẹ gbogbo ẹni to ba wa niluu patapata ni yoo ṣatilẹyin fun ẹgbẹ oṣelu kan ṣoṣo, tabi ti yoo nifẹẹ si ọrọ oṣelu fun idi kan tabi omi-in. Debọ ni, ‘‘Idi ta a fi n ṣe ijọba awa-ara-wa naa ni ki onikaluku ni ẹtọ labẹ ofin lati ṣe ohun to ba fẹ, to si ba ofin mu, lai jẹ pe ẹnikẹni dunkooko tabi halẹ mọ ọn. Ko waa ni i daa ki awọn kan maa waa dunkooko mọ ẹni kan, tabi ki wọn maa bu u, tabi ki wọn maa wa gbogbo ọna lati ba a lorukọ ẹ jẹ, nitori ko ṣatilẹyin fun ẹni ti wọn fẹ.’’

Lori ikanni abẹyẹfo rẹ (twitter), ni oṣere naa kọ ọrọ si, to si kọminu lori bi awọn alatilẹyin APC ṣe maa n gbe oun ṣepe, ti wọn si maa n sọrọ si, ti wọn tun maa n bu awọn obi rẹ, ti wọn si n wa gbogbo ọna lati ba a lorukọ jẹ.

Mr Macaroni ni, ‘‘Ojoojumọ ni awọn aja APC maa n kọju ija si mi, ti wọn maa n sọ ọrọ abuku si mi. Wọn maa n ṣepe fun mi, wọn tun n ṣepe fawọn obi mi, gbogbo ọna ni wọn si n wa lati ba orukọ mi jẹ. Awọn alatako yii kan naa wa ninu ijọba to doju ija kọ mi, ti wọn si ṣe mi ṣakaṣaka lọjọsi.

“Ṣugbọn ko si wahala o, a maa pade nibi IPADE ITA GBANGBA’’.

Nigba ti akọroyin wa pe oṣere yii lori aago lati mọ ohun to fa ọrọ to kọ sori ikanni Twitter rẹ yii, Adebọwale ni, ‘‘Mi o mọ ohun ti mo ṣe fun awọn APC. Loootọ ni wọn ti ran oriṣiiriṣii eeyan si mi pe ki n waa ṣatilẹyin fun awọn oludije wọn kan, ṣugbọn mo sọ pe mi o ṣe oṣelu, nitori ko ba ilana iṣẹ ti mo gbe dani mu. Mi o si ro pe eleyii yẹ ko mu ija wa, tabi ko fa ibanilorukọ jẹ tabi idunkooko mọ ni. Ṣugbọn niṣe ni wọn maa n bu mi, ti wọn maa n fẹnu ṣaata iṣẹ ti mo n fi oogun oju mi ṣe, ti wọn si maa n ṣepe fun emi atawọn obi mi.

O ti pẹ ti wọn ti maa n ṣe bẹẹ fun mi ti mi o ki i sọrọ, ṣugbọn mo kan pinnu lati sọrọ jade bayii ni. Gbogbo wa ko le sun ka kọri si ibi kan naa, ki i si i ṣe gbogbo awọn to wa niluu Eko, tabi gbogbo awọn oṣere tabi ilu mọ-ọn-ka ni wọn n ṣe atilẹyin fun ẹgbẹ kan ṣoṣo, tabi ti wọn tilẹ nifẹẹ si oṣelu paapaa, onikaluku ni anfaani lati ṣatilẹyin fun ẹni kan tabi ko sọ pe oun ko ṣe, niwọn igba ti ki i ti i ṣe tipatipa.”

Bẹẹ ni Mista Makaroni wi o

Leave a Reply