Adewale Adeoye
Iwaju Onidaajọ Abilekọ S.M Akintayọ, tile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa ni Mapo, niluu Ibadan, ipinle Ọyọ ni awọn tọkọ-taya meji kan, Ọgbẹni Moshood Kani ati iyawo rẹ, Abilekọ Taibat Kani, gbe ara wọn lọ. Ọgbẹni Moshood lo gbe iyawo rẹ yii lọ sile-ẹjọ ọhun pe ki adajọ tu igbeyawo ọdun meje to wa laarin awọn mejeeji ka loju-ẹsẹ, ki kaluku awọn le maa gbe layọ ati alaafia lọtọọtọ.
Mọshood ṣalaye niwaju adajọ pe, ‘Oluwa mi, ẹ jọwọ, ẹ ba mi tu igbeyawo to wa laarin emi pẹlu iyawo mi yii ka loju-ẹsẹ, ọrọ rẹ ti su mi patapata, ki i ṣe iyawo to yẹ ko maa ba eeyan gbele rara. Kẹ ẹ si maa wo o, ọdun keje ree ti mo ti gbe e sile gẹgẹ bii iyawo, ṣugbọn mi o figba kankan gbadun rẹ ri ninu ile. Kọrọ ma ti i ṣẹlẹ laarin wa ni, ṣe niyawo mi maa lọọ yọ ọbẹ si mi, ti yoo si maa fi le mi kaakiri. Mi o mọ boya o ti gbe ni gareeji awọn onimọto tẹlẹ ni.
‘‘O tun jẹ ẹni to n jale, gbogbo ẹru inu ile mi lo ti ji ko sa lọ patapata. Ti ọrọ ba ti ṣe bii ọrọ laarin emi pẹlu rẹ, ṣe lo maa kẹru rẹ jade ninu ile mi, o si le lo to ọsẹ meji tabi ju bẹẹ lọ nita ko too tun pada wa sile. Ko sifẹẹ kankan mọ laarin wa, idi ree ti mo fi n rọ adajọ ile-ẹjọ yii pe ko tu wa ka. Ṣugbọn ki wọn jẹ ki n maa ṣetọju awọn ọmọ to wa laarin igbeyawo wa, niwọn igba to kuku jẹ pe emi yii kan naa lo n ṣetọju awọn ọmọ ọhun nigba ti iya wọn ba kuro nile mi.
‘‘Ọlọrun kuku ṣe e, mi o ti i sanwo ori rẹ lọdọ awọn obi rẹ rara, mo kan lọọ mọ awọn obi rẹ nikan ni, ko sigba ta a maa ja nile bayii, ṣe niyawo mi maa n halẹ mọ mi pe oun maa pa mi ni, mi o si ti i fẹẹ ku bayii ni mo ṣe n bẹbẹ pe kile-ẹjọ tu wa ka o.
Ba a ba ti ja bayii, iyawo mi aa ti lọ siluu wọn, mi o mọ ohun to n lọọ ṣe nibẹ nigba gbogbo. Bẹẹ bi mo ba mọ pe bi yoo ṣe yọwọ ree nigba ta a n fẹra wa sọna ni, mi o ni i dabaa lati fẹ ẹ rara. Abamọ nla gbaa lọrọ ọhun jẹ fun mi.
Niwọn igba ti ko ti si olujẹjọ, iyẹn Abilekọ Taibat Kani, nile-ẹjọ ọhun, adajọ sun igbẹjọ si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2024.
Bakan naa lo kan an nipa fawọn akọwe kootu pe ki wọn ri i daju pe wọn fiwe ipẹjọ tuntun ọhun le olujẹjọ lọwọ, ko le yọju sile-ẹjọ ọhun lakooko ti igbẹjọ maa waye lori ọrọ rẹ.