Monisọla Saka
Shehu Sani, ti i ṣe aṣofin to n ṣoju ẹkun Aarin Gbungbun Kaduna tẹlẹ, ti kilọ fawọn ọmọ Naijiria lati pe aaro ati ọdọfin inu wọn, ki wọn too tẹwọ gba owo ti Tinubu loun fẹẹ maa fun wọn.
Ọkunrin ọmọ bibi ipinlẹ Kaduna yii ni kawọn eeyan ro o daadaa ki wọn too gba ẹgbẹrun mẹjọ ti ijọba Tinubu n fọnrere ẹ, ko ma baa lọọ da bii owo to ni wọn ti fi nnkan si, ti wọn pin ni ẹgbẹrun mẹwaa mẹwaa, lasiko ijọba Aarẹ Buhari, eyi to pada tun ja si iṣẹ ati oṣi fawọn eeyan naa.
Lori ẹrọ abẹyẹfo Twitter rẹ to kọ ọ si, lo ti ni, “Awọn ti wọn gba ẹgbẹrun mẹwaa owo ẹ̀rẹ ti Buhari pin lọjọsi pada talaka ju ekute ṣọọṣi lọ ni. Ẹ ro o daadaa, kẹ ẹ si gbadura kẹ ẹ too tẹwọ gba ẹgbẹrun mẹjọ ti wọn n gbe bọ yii”.
O ni owo ti ko le gbọn ìṣẹ́ danu lara awọn eeyan nijọba ni awọn maa fun araalu.
Latigba ti Tinubu ti fi erongba rẹ han lati maa fun awọn ti iṣẹ ati oṣi n ba finra niluu ni ẹgberun mẹjọ Naira fun oṣu mẹfa ni awọn eeyan ati ẹgbẹ loriṣiiriṣii ti n sọ iha ti wọn kọ si igbesẹ naa. Bawọn kan ṣe n gboṣuba kare fun un pe igbesẹ daadaa lo gbe, nitori bo ṣe ni aanu awọn eeyan loju. Bẹẹ lawọn mi-in ni ète oṣelu lasan ni owo ti Tinubu n pariwo pe oun fẹẹ fi ran awọn eeyan lọwọ.
Tẹ o ba gbagbe, Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keje, ọdun yii, ni awọn aṣofin buwọ lu aba eto ẹyawo ti Tinubu gbe siwaju wọn.
Owo yii lo ni awọn yoo ṣeto ẹgbẹrun mẹjọ mẹjọ ninu ẹ fodidi oṣu mẹfa, fawọn ọmọ Naijiria bii miliọnu mejila, lati mu ki wahala ati inira ti owo iranwọ epo ti wọn yọ ko ba wọn.
Owo tijọba Tinubu n beere fun yii lo ṣalaye sinu lẹta to fi ranṣẹ sawọn aṣofin pe awọn yoo fi ṣọwọ sinu apo banki awọn eeyan tawọn ba yan fodidi oṣu mẹfa.