Ẹ jade lati dibo fẹni to ba wu yin, a ti ṣeto aabo to peye-Kọmisanna ọlọpaa Kwara 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Gẹgẹ bi gbogbo awọn olugbe ipinlẹ Kwara ṣe n gbaradi lati kopa nibi eto idibo ijọba ibilẹ ti yoo waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2024 yii, jake-jado ipinlẹ naa, Kọmisanna ọlọpaa Kwara, Victor Ọlaiya, ti ni kawọn araalu fọkanbalẹ, ki won si jade lati dibo, nitori aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia wọn.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ni Kwara, Ejirẹ Adeyẹmi Adetoun, fi sita l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan-an,  ni kọmisanna ti ni ki gbogbo oludibo lọọ fọkanbalẹ, aabo to peye wa fun ẹmi ati dukia wọn.

O tun rọ gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara patapata lati jade lọpọ yanturu lati ṣe ojuṣe wọn nipa didibo fun ẹni to ba wu wọn, nitori pe awọn ẹṣọ alaabo yoo lu igboro pa lati peṣe aabo fun ẹmi ati dukia wọn, tawọn yoo si daabo bo wọn titi ti eto idibo naa yoo fi pari.

Ọlaiya ni ki awọn araalu mọ foya, ki wọn si ma tẹ ofin loju lasiko idibo. Bakan naa ki wọn fọwọsowọpọ pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to ba wa lẹnu iṣẹ.

Ni igunlẹ ọrọ rẹ kọmisanna ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, ko ni ko ni kaaarẹ ọkan lati maa peṣe aabo faraalu, awọn yoo si ṣiṣẹ karakara pẹlu awọn ọlọpaa obinrin lati ri i pe gbogbo nnkan n lọ ni irọwọ-rọsẹ, ti eto idibo naa yoo si kẹṣẹ jari.

 

Leave a Reply