Ẹ jẹ ka fẹṣọ yanju ọrọ awọn Fulani, tori awọn ọmọ wa ti wọn wa lọdọ wọn – Imaamu Ọfa

Florence Babaṣọla

 

Imaamu agba fun ilu Ọfa, nipinlẹ Kwara, Fadilatu Sheikh Alhaji Muyideen Salman, ti sọ pe ẹṣọ pẹlẹ nikan la le fi yanju wahala to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ laaarin iran Yoruba atawọn ara Ariwa orileede yii, ki ọrọ naa ma baa yọri si ohun ti a ko lero.

Nibi ayẹyẹ wiwe lawani fun Aarẹ Musulumi ilu Ifọn-Orolu, nipinlẹ Ọṣun, Alhaji (Ẹnjinia) Isiaq Ọlajide Ọlarinde, ni Sheikh Salman ti woye pe okun ki i ho ruru, ka wa a ruru.

O ṣalaye pe ko si nnkan ti pẹlekutu ko le yanju, ati pe bo ti le wu ki iran Yoruba maa binu to, ti wọn ba pepade alaafia pẹlu awọn eeyan Ariwa, ti onikaluku tu ẹdun ọkan rẹ jade, yoo so eso rere ju rogbodiyan lọ.

Sheikh Salman ran awọn ẹya Yoruba leti pe ọkẹ aimọye ọmọ wọn lo wa niha Ariwa ti Eledua ti gba fun; ti wọn ti ni dukia rẹpetẹ, ti wọn si n ṣalubarika nibẹ.

O ni ti wahala to n ṣẹlẹ lọwọ lapa Guusu Iwọ-Oorun orileede yii ba burẹkẹ ju bayii lọ, afaimọ ko ma ṣakoba nla fun awọn ọmọ Yoruba to wa lọdọ tiwọn naa.

Gẹgẹ bo ṣe wi, “Ẹ jẹ ka rọra ṣe e, ẹ dakun, agbalagba lawa ni ko jẹ ka ba yin da si gbogbo yanmuyanmu ti ẹ n ṣe kaakiri yẹn, amọ, ẹ jẹ ka ranti pe ẹni to ba ti sin owo ju, ẹni ti baba tiẹ naa jẹ lowo yoo jade o.

“Awọn ọmọ wa kun ọhun, ẹ jẹ ka fẹṣọ ṣe, ti wọn ba le awọn ti wọn n ṣalubarika wa lọhun-un wale, ofo de niyẹn, gbogbo nnkan pẹlẹpẹlẹ, ka jokoo papọ, ka yanju nnkan lo dara, ki i ṣe laasigbo, laasigbo o le ṣe nnkan kan, nnkan to maa da silẹ, agbara rẹ ko ni i ka a mọ, ọrọ mi fun gbogbo ilẹ Yoruba niyẹn”

Nibi ayẹyẹ naa ni Sheikh Salman ti kilọ fun Aarẹ Musulumi Ifọn-Orolu ti wọn we lawani fun lati maa ṣe ohun gbogbo pẹlu ọgbọn Ọlọrun ati ikiyesara. O ni ko gbọdọ maa sọrọ ju, ko si gbọdọ yan oloṣelu kankan laayo nitori wọn yoo maa ṣọ ọ lọwọlẹsẹ ni.

Aarẹ tuntunn ọhun, Alhaji Ọlarinde, dupẹ lọwọ Kabiesi ilu Ifọn-Orolu, Ọba Al-Mah’ruf Adekunle Magbagbeọla, Olumoyero Keji, fun anfaani nla to fun un, o si ṣeleri lati jẹ aṣoju ati aṣaaju rere fun ẹsin Islam ati fun ilu naa lapapọ.

Lara awọn ti wọn wa nibi ayẹyẹ naa ni Grand-Imam ilu Ilọrin, Fadilatu Sheikh Dr. Muhammad Bashiru Soliu, Imaamu agba tiluu Ibadan ati tilẹ Yoruba lapapọ, Sheikh Abdulganiyy Abubakri, Imaamu agba funpinlẹ Ọṣun, Sheikh Musa Animaṣahun ati Imaamu agba fun ilu Ifọn-Orolu, Alhaji Sheikh Muhibbullah Abdus-Salam Adeṣina 111.

Leave a Reply