Adewale Adeoye
B’ọrọ ti gbajumọ oniṣowo to tun jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ Dangote-Group, Alhaji Aliko Dangote, sọ ba ṣee tẹle, a jẹ pe inu oṣu Kẹfa, ọdun 2024 yii, lopin maa de si bijọba ilẹ wa ṣe maa n lọọ fọ epo bẹntiroolu wa lati Oke-Okun nigba gbogbo. Ọkunrin naa ni iṣẹ ti n lọ labẹnu bayii lati fopin si igbesẹ yii, ti epo bẹntiroolu, diisu ati epo tawọn ọkọ baaluu maa n lo, eyi ti wọn n lọọ fọ wa lati Oke-Okun yoo si dopin.
Alhaji Aliko Dangote sọrọ ọhun di mimọ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, nibi eto awọn oniṣowo pataki kan ti wọn pe e si ni Kigali, lorileede Rwanda, lọhun-un.
O ni ileeṣẹ ifọpo tuntun toun ṣẹṣẹ ṣe kunju oṣuwọn to lati pese epo bẹntiroolu, diisu ati epo tawọn ọkọ baaluu maa lo fun gbogbo Iwọ Oorun ilẹ Adulawọ bayii.
Siwaju si i, Dangote ni laarin ọdun mẹrin si akoko yii, ileeṣẹ oun maa le pese ajilẹ tawọn agbẹ ilẹ Adulawọ maa lo, ti a ko si ni i maa lọ s’Oke-Okun mọ lati lọọ maa ko awọn ajilẹ naa wa gẹgẹ ba a ṣe ti n ṣe lọwọ bayii.v