Irọ ni wọn n pa o, Ọṣinbajo ko juwọ silẹ fun ẹnikẹni lori ibo abẹle APC-Akinọla

Ọrẹoluwa Adedeji
Ẹgbẹ kan to n ṣe ipolongo fun Igbakeji Aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo, lati dupo aarẹ ilẹ wa, (Ọṣinbajo Presidential Campaign Council), ti sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ ọrọ kan to n lọ kaakiri pe Igbakeji Aarẹ naa ti sọ pe oun ti juwọ silẹ pe oun ko dije mọ. Wọn ni irọ to jinna soootọ ni, ati pe awọn oniṣẹẹbi kan lo wa nidii ọrọ yii.
Ninu atẹjade kan ti Ọgbẹni Richard Akinọla fi sita lorukọ ẹgbẹ naa ti wọn fi ranṣẹ si ALAROYE ni wọn ti ṣalaye pe ẹru bi ọpọ awọn eeyan ṣe n ṣatilẹyin fun Ọjọgbọn Ọṣinbajo, ati bi awọn alatilẹyin rẹ ṣe n fojoojumọ pọ si i lo n ba awọn ti wọn n gbe iroyin ofege naa kiri.
‘‘A fẹ ki ẹ mọ pe ko si igba kankan ti Ọṣinbajo ronu lati gbe iru igbesẹ yii, nitori oun ni oludije to n ṣaaju ninu gbogbo awọn to ku, bẹẹ ni igbimọ ti ẹgbẹ APC gbe kalẹ lati ṣayẹwo awọn oludije paapaa fidi eyi mulẹ pe oun lo n lewaju ninu gbogbo awọn oludije. Ko ṣee ṣe fun iru eeyan bẹẹ lati waa sọ pe oun ko ṣe mọ, fun ti kin ni?
‘‘Ọṣinbajo ti n gbaradi fun eto idibo abẹle ti yoo waye, idaniloju si wa pe oun ni yoo jawe olubori.’’
Bakan naa ni wọn tun sọ pe ko si ootọ ninu ahesọ mi-in ti wọn tun n gbe kiri pe Ọṣinbajo sọ pe ki awọn aṣaaju ẹgbẹ APC nilẹ Yoruba ṣe nnkan kan fun oun, oun naa si ni pe ki wọn jẹ ki oun lọọ ri Pasitọ Adeboye ki oun too juwọ silẹ, wọn ni irọ buruku gbaa ni, ko si ohun to jọ bẹ, ki awọn eeyan, paapaa ju lọ awọn aṣoju ti yoo dibo ati awọn alatilẹyin awọn ma gba iru ọrọ bẹẹ gbọ. Irọ to jinna sootọ ni.

Leave a Reply