Ẹ ma mikan lori owo tijọba n ya, ko ti i pọ ju agbara wa lọ – Buhari

Faith Adebọla

Aarẹ ilẹ wa, Mohammadu Buhari, ti ṣalaye pe ko si idi fẹnikẹni lati foya tabi ko ọkan soke latari awọn ẹyawo tijọba Naijiria n ya lọdọ awọn orileede agbaye, o ni kinni naa ko le mu iṣoro wa, tori ẹyawo naa ko ti i pọ ju ohun ti apa ijọba apapọ ka lọ, awọn naa o si kawọ gbera nipa ẹ.

Niwaju awọn ọmọ ileegbimọ aṣofin apapọ ni Buhari ti sọrọ yii l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, lasiko to n ka bọjẹẹti, iyẹn aba eto iṣuna owo ọdun 2022 to gbe kalẹ siwaju awọn aṣofin naa.

Aarẹ ni: “Awọn kan ti n sọrọ nipa ba a ṣe n yawo, wọn lo n kọ awọn lominu jọjọ, wọn niṣe lo jọ pe a n jẹ gbese lati san gbese. Ọrọ wọn ye mi, bo si ṣe yẹ ki wọn ṣe naa niyẹn.

Ṣugbọn awa mọ pe gbese tijọba apapọ jẹ ko ti i kọja gejia, o ṣi wa labẹ ohun ti apa wa ka. Tori awọn iṣẹ idagbasoke pato kan la ṣe n yawo, awọn iṣẹ ti a si n fowo naa ṣe ki i ṣe oja okunkun rara, arun oju ni, ko sẹni ti o le ri wọn.

Ẹẹmeji ọtọọtọ ni ọrọ-ajẹ orileede yii ti tẹnu bepo laarin saa iṣakoso yii, sibẹ a tun ta a ji, owo la si n na lawọn asiko bẹẹ, eyi si wa lara nnkan to maa n sun wa dedii ẹyawo. Ta o bo fowo peena owo niru asiko bẹẹ, ko si bi ọrọ-aje ko ṣee ni i wogba patapata.

A ti n ṣeto lati jẹ ki owo ti a oo maa pa wọle labẹle tubọ gbe pẹẹli si i, iyẹn lo maa jẹ ko ṣee ṣe lati san gbese ọrun wa lai mu wahala pupọ dani. Ka sọrọ sibi tọrọ wa, iṣoro ti a ni ki i ṣe bi a ṣe maa san gbese, ṣugbọn bi a ṣe maa ri owo pa wọle sapo ijọba daadaa.

“A n gbero lati na aropọ owo ti iye rẹ to tiriliọnu marun-un naira, aadọrun-un biliọnu naira latinu owo awọn dukia ijọba ta a sọ di ti aladaani sori sisan ele ori gbese, ibẹ naa la si maa na tiriliọnu kan ati diẹ naira ta a maa ri lori awọn ẹyawo tawọn mi-in ya lọwọ ijọba apapọ si.”

Leave a Reply