Ẹ ma parọ mọ wa o, ẹgbẹ APC kọ lo ṣokunfa wahala eto ọrọ-aje to n dojukọ Naijiria – Owoẹyẹ

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Olori awọn aṣofin ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọnarebu Timothy Owoẹyẹ, ti sọ pe aimọkan lo fa a ti awọn kan fi n pariwo kaakiri bayii pe ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), lo ṣokunfa wahala eto ọrọ aje to n ṣẹlẹ lorileede Naijiria bayii.

O ni oniruuru igbesẹ ti Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu n gbe lọwọlọwọ to da bii pe o mu inira ba awọn araalu lo jẹ eyi to pọn dandan, ki gbogbo nnkan le pada bọ sipo.

Ọwoẹyẹ sọrọ yii niluu Oṣogbo, lasiko to n ṣalaye oniruuru eto ti wọn ti la kalẹ lati fi ṣe ayẹyẹ aadọrin ọdun ti gomina ana l’Ọṣun, to jẹ minisita fun ọrọ okoowo ori-omi bayii, Alhaji Gboyega Oyetọla, de oke eepẹ.

O ni ọrọ Naijiria da bii amunkun ti awọn eeyan n wo pe ẹru ori rẹ wọ ni, lai ṣakiyesi bi ẹsẹ rẹ ṣe ri. O sọ siwaju pe nnkan ti bajẹ jinna, Tinubu kan ṣe kongẹ asiko to pọn dandan lati mu atunṣe ba gbogbo rẹ ni.

Owoẹyẹ fi da awọn araalu loju pe laipẹ laijinna ni gbogbo nnkan yoo duroore, ti yoo si ri bi olukuluku ṣe n fẹ. O ni odidi ọjọ marun-un lawọn yoo fi dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbesi aye Oyetọla, ẹni ti ayẹyẹ ọjọọbi rẹ ṣe kongẹ oriire ti ẹgbẹ APC ṣe ninu idibo gomina ipinlẹ Edo.

Lara alakalẹ eto naa ni ipese iwosan-ọfẹ fawọn eeyan agbegbe Oṣogbo, Iwo, Ileṣa ati Iragbiji. Bakan naa ni wọn yoo si pin oniruuru ounjẹ fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun.

O sọ siwaju pe afojusun eeyan ẹgbẹrun kọọkan lawọn ni kaakiri agbegbe ti iwosan ọfẹ yoo ti waye ọhun, bẹẹ lawọn yoo gbe ounjẹ kaakiri ṣọọṣi ati mọṣalaaṣi.

Lori idibo ijọba ibilẹ to n bọ loṣu Keji, ọdun 2025, nipinlẹ Ọṣun, Owoẹyẹ sọ pe ẹgbẹ naa ti mura tan, gbogbo aye yoo si mọ pe digbi lawọn wa nigba ti esi idibo naa ba jade.

Leave a Reply