Ẹ maa gun kẹkẹ, o dara fun ilera ara yin- FRSC 

 Ibrahim Alagunmu, Ilọrin 

 Afi ki gbogbo ọmọ Naijiria yaa pa mọto ti bayii, ki onikaluku lọọ ra kẹkẹ lati maa gun un lọ sibikibi to ba fẹẹ lọ, nitori wọn ti jẹ ko di mimọ bayii pe kẹkẹ gigun dara fun ilera wa.

Ọga agba ajọ ẹṣọ alaabo oju popo ni Kwara (FRSC), Ọgbẹni Frederick Ogidan, lo gba awọn araalu nimọran pe ki wọn maa gun kẹkẹ alafẹsẹ-wa, o lo dara gidigidi fun ilera ara wọn.

Ogidan lo sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọkKọkandinlogun, oṣu Karun-un yii, niluu Ilọrin, lasiko to n ba akọroyin Ajọ akoroyinjọ ilẹ wa, NAN, sọrọ lati fi sami ayaajọ aabo ọsẹ lagbaaye (United Nations Global Safety Week). Bakan naa lo kilọ pe kawọn dẹrẹba yẹra fun wiwa ọkọ to n ṣeefin loju popo, tori pe o lewu fun ilera araalu ati ayika wọn.

Ọkunrin naa ṣalaye pe awọn eefin to n jade lara ọkọ lewu fun ilera, bakan naa lo le sakoba fun ilera araalu ati ayika wa gbogbo. O ni o tun le ṣokunfa ijamba oju popo fun ọkọ miiran to n bọ lẹyin eyi to n seefin ọhun. O tẹsiwaju pe o yẹ ka wa ohun irinsẹ to n gbe ni rinrin-ajo ti yoo mu irọrun wa, ti yoo si la ipa rere lawujọ.

Ogidan ni kẹkẹ gigun lo dara ju lọ fun irinṣẹ. Yatọ si pe o jẹ ohun idaraya to dara fun ilera, kẹkẹ ki i ṣe eefin kankan to le ṣe akoba fun ayika. O ni ki awọn eniyan maa lo ọkọ to n lo ina ẹlẹntiriiki, ki wọn maa gun kẹkẹ, ki wọn maa gun reluwee ati awọn ọkọ ti eefin wọn ko pọ lo dara ju lọ lati maa gbe  rinrin-ajo.

Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o ni ki awọn araalu yẹra fun ọkọ to n ṣeefin, ọkọ ti taya rẹ ko dara, ki wọn si gbiyanju lati maa ṣabẹwo silẹ mẹkaliiki loorekoore fun atunse ọkọ wọn, eyi to ni yoo mu lilọ-bibọ rọrun pẹlu eyikeyii ohun ta a ba fẹẹ gbe rinrin-ajo naa.

Leave a Reply