Ọlawale Ajao, Ibadan
Lẹyin ti awọn ẹgbẹ ajìjagbara Yoruba, Oodua People’s Congress, ti mu jagunjagun awọn Fúlàní nni, Iskilu Wakili, nitori awọn iwa ọdaran to máa n hu niluu Ayétẹ̀, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, awọn ti ọkunrin Fúlàní naa ti ṣèjàǹbá fún ti bẹrẹ sí í royin itú to fi wọn pa.
Lara wọn ni Ọdọmọfin ilu Ayetẹ, Oloye Saubana Omileke Oyewọle, ẹni tí Wakili deede dana sun oko kòkó mọlẹbi ẹ̀ lai jẹ pe wọn ṣe nnkan kan fún un tabi pe ija wa laarin wọn tẹlẹ.
Tẹ o ba gbagbe, ni nnkan bíi oṣù meji sẹyin lajìjàgbara fún ilẹ Yorùbá nni, Olóyè Sunday Adeyẹmọ (Sunday Igboho), lọọ le awọn ọdaran to wa láàrin àwọn Fúlàní kúrò lagbegbe Ibarapa.
Awuyewuye to tẹ̀yìn ọrọ yii yọ lo mu ki ìjọba ipinlẹ Ọyọ ran awọn aṣoju lọ silẹ Ibarapa lati ba awọn aṣáájú Yoruba atawọn Fúlàní ti ko ti i fi agbegbe naa silẹ sọrọ ko too di pe gomina ipinlẹ Ọyọ Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde funra rẹ lọ sibẹ lati ri i pe ibagbepọ alaafia jọba laarin awọn olugbe agbegbe yii.
Ṣugbọn lẹyìn ìpàdé alafia ti ìjọba ṣe láwọn ara ilu Ayétẹ̀ ati agbegbe ẹ̀ tun n fojoojumọ kigbe pe ki gbogbo ayé gba àwọn lọwọ baba ẹni ọdun marundinlọgọrin (75) ti wọn n pe ni Wakili yii.
Wọn lọkunrin jagunjagun awọn Fúlàní yii lo wa nidii ọpọlọpọ ipaniyan ati ijinigbe to saaba máa n waye lagbegbe naa.
Oloye Oyewọle ṣalaye pe “Yatọ si Sarikin Fulani to wa niluu Igangan, (ṣugbọn to ti sa lọ si Ilọrin nitori bi Sunday Igboho ṣe kilọ fun un lati fi ipinlẹ Ọyọ silẹ) ko si ẹni to tun n ko ipaya ba awọn eeyan lagbegbe yii ju Wakili lọ.
“Nigba ti ọrọ Wakili ka wa laya, meje ninu awọn ọ̀dọ́ ilu yìí (Ayétẹ̀) lọọ ba a lábúlé ẹ lati kìlọ fún un pe ko jáwọ́ ninu awọn iwa ọdaran to n hù.
Lọjọ ti awọn ọdọ lọọ ba a nile gan-an lo lọọ fibinu dana sun oko kòkó ẹgbọn mi. Eékà mẹwaa ni koko yẹn, ko jinna si abúlé ti Wakili n gbe.
“Lóòótọ́, ẹgbọn mi lo ni oko yẹn, ṣugbọn mọlẹbi wa lo ni ilẹ̀ ti wọn fi dako naa.
“Mo máa n rọ awọn eeyan mi lati bọ̀wọ̀ fófin, ki wọn sì má ṣe ba Fúlàní ja lati le faaye gba ibagbepọ alaafia laarin ẹ̀yà mejeeji, ṣugbọn ibọn AK47 ni Wakili atawọn ọmọ ẹ máa n gbe rin kiri ní tiwọn.”
“Pẹlu bi awọn Fulani ṣe n ṣe wọnyi, o daju pe wọn ti gbaradi daadaa fun ogun. Bi wọn ba si ni ibọn ju bẹẹ lọ, koda ko kọja AK47 ti wọn n gbe kiri, wọn o le bori wa.
“Didakẹ ti awa dakẹ ki i ṣe tí pe awa naa ko le jà, ẹru ijọba la kan n ba, òfin ilẹ yii ti a n bọ̀wọ̀ fun ni ko jẹ ká lè gbẹsan gbogbo iya ti wọn fi n jẹ wá.”