Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ẹgbẹ People’s Democratic Party (PDP) ipinlẹ Ekiti ti fẹsun kan Gomina Kayọde Fayẹmi pe o fẹẹ dọgbọn gba ilẹ awọn eeyan ipinlẹ naa lati kọ ibudo ti wọn ti n sin maaluu fawọn Fulani darandaran.
Ẹgbẹ naa ni ti iru ẹ ba fi le waye, ọkan awọn eeyan ipinlẹ naa yoo bajẹ, nitori igbagbọ ti wọn ni ninu ilẹ awọn baba-nla wọn, eyi yoo si fi iya nla jẹ wọn.
Eyi jẹ yọ ninu atẹjade kan ti akọwe ipolongo ẹgbẹ naa, Raphael Adeyanju, fọwọ si lọjọ Ẹti, Furaidee, ninu eyi to ti sọ pe ibudo mẹfa ọtọọtọ to wa ni Omuo-Ekiti, Emure-Ekiti, Oke-Ako, Ọtun-Ekiti, Okemẹsi and Ipole Ilọrọ ni Fayẹmi fẹẹ fun awọn Fulani.
Adeyanju ni iwa buruku gbaa ni igbesẹ naa, awọn to fẹ ilọsiwaju Ekiti ko si ni i gba iru ẹ laaye laelae nitori o kọja ọrọ ẹsin ati oṣelu.
Akọwe ipolongo naa ni laipẹ yii ni gomina yoo fọgbọn gbe ofin kan kalẹ lati gba ilẹ, eyi ti yoo parọ pe wọn fẹẹ fi ṣe eto ọgbọn ki ounjẹ le pọ lọpọ yanturu, ṣugbọn awọn fura pe o fẹẹ fi tu awọn Fulani loju ni nitori ipo aarẹ Naijiria to fẹẹ du.
‘‘Ilana ti Fayẹmi fẹẹ lo ni ko fun awọn Fulani ni ibudo meji meji ni ẹkun idibo mẹta ta a ni, ọgbọn lo si fẹẹ fi gba wọn nipasẹ ileeṣẹ eto ọgbin.
‘‘A gbọ lọdọ awọn ta a le finu tan pe iforukọsilẹ tijọba ni kawọn Fulani ṣe laipẹ yii wa fun mimọ iye wọn ati iye ibudo ti wọn yoo nilo. Pẹlu iforukọṣilẹ yii, wọn ṣi n kọ lu awọn agbẹ loko, ko si si ẹnikan kan tijọba mu.
‘‘Awọn ọba alaye kan ti wọn gbọ nipa ẹ pariwo sita laipẹ yii, eyi lo mu kijọba fẹẹ gba ọna mi-in.’’
Ẹgbẹ PDP ni lai fi ti oṣelu ṣe, ijinigbe to n waye l’Ekiti lẹnu ọjọ mẹta yii n ba gbogbo eeyan lọkan jẹ, bẹe lawọn eeyan ọhun ko tiẹ bọwọ fawọn ori ade.
Wọn waa ni ki gbogbo awọn to fẹran Ekiti bẹ Fayẹmi ko ma fi ẹmi araalu tafala nitori oṣelu.
Ṣugbọn ẹgbẹ All Progressives Congress (APC) ti sọ pe ki PDP fi oṣelu imẹlẹ silẹ, ki wọn gbaruku ti Fayẹmi lati gbe Ekiti soke.
Ninu atẹjade kan ti adari ẹka iroyin ati ipolongo, Alaga Sam Oluwalana, fi sita lo ti sọ pe irọ gbaa ni ẹsun ti PDP fi kan Fayẹmi, ati pe nnkan ti wọn n sọ ko si ninu eto ijọba rara.
O ni latigba ti ijakulẹ ti ba wọn nibi ipade apapọ ẹgbẹ wọn l’Oṣogbo ni PDP ti n wa ọna lati ṣi oju awọn eeyan kuro lọdọ wọn, eyi ni wọn ṣe n pariwo ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ.
Oluwalana ni tijọba ba tiẹ fẹẹ lo ilẹ fun ohunkohun, wọn yoo gba ọna to tọ, wọn yoo si sanwo fawọn to ba tọ si, ẹri eyi si wa lọdọ awọn ti wọn gbalẹ lọwọ wọn lati kọ papakọ-ofurufu.
O waa ni awọn eto ọgbin tijọba fẹẹ ṣe yoo ran awọn ọmọ ẹgbẹ PDP ati mọlẹbi wọn lọwọ, ki wọn yaa gbaruku ti Fayẹmi ki ounjẹ le pọ yanturu.