Ọlawale Ajao, Ibadan
Iya ẹni ọdun mẹtadinlaaadọrin (67) kan, Alhaja Modupẹ Animaṣahun, ti pe pasitọ ṣọọṣi igbalode kan nigboro Ibadan, Pasitọ Ẹ̀rí Ṣèyí lẹjọ, o lo kọ̀ lati san gbese owo to ya lọwọ oun lati ra ilẹ to fi da ṣọọṣi silẹ.
L’Ọjobọ, Tọ́sìdeè, to kọja, niya naa parọwa ọhún níwájú igbimọ àwọn adájọ kootu ìbílẹ̀ Ọjaba to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan.
Alhaja Animaṣahun, oníṣòwò to fi adugbo Orita-Aperin, n’Ibadan, ṣebugbe, sọ pe ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ ni tenanti oun yii fi ko àwọn eyi to nilaari ninu ẹru rẹ jade ninu ile oun.
O ni lẹyìn oṣù bíi mẹfa to ti kuro ninu ile, tí àwọn kò sí ti i gbúròó ẹ̀ dasiko yii, lawọn too mọ pé àgádágodo to ti bàjẹ́ lọkùnrin náà fi dígẹrẹu sí ẹnu ìlẹ̀kùn yara mejeeji to rẹ́ǹtì ninu ile oun.
Gẹgẹ bo ṣe ṣàlàyé, “Ayalegbe mi ni pasitọ, o gba yara meji ni wáún taosàn (N1,000) loṣu.
“O ya 42,000 lọwọ mi lati lọọ fi gba ilẹ̀ to fi n ṣe ṣọọsi. Gbogbo ẹ̀ kò tiẹ̀ dùn mi bíi apẹ-irin mi to fi pọ́n mọ́ínmọ́ín lọjọ ajọdun. Ìyẹn ni mo tiẹ fẹ ko ba mi da pada.
“O tun gbe sìlíńdà gáàsì ti mo ra ni nain taosàn (9,000) naa. O si ti kuro ninu ile bayii. Lẹyin to ṣe ajọdun to tori ẹ̀ ya àwọn nnkan mi wọnyi lo lọ ta a ko ri i mọ.
“Gbogbo ẹru rẹ lo ti fẹẹ ko kuro ninu ile tan. O waa fi kọkọrọ ti ko dáa tilẹkun. Mo fẹ ki ile-ẹjọ ba mi gba owo to jẹ mi, ko si kuro ninu ile mi.”
Ile-ẹjọ, labẹ akoso Oloye Ọdunade Ademọla, ti paṣẹ pe ki pasitọ san gbogbo owo to jẹ Alaaja, ko si ko gbogbo ẹru ẹ kuro nile naa, o pẹ́ tan, ki oṣu keji, ọdun 2021 yii too pari.