Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Ọwọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti tẹ ọkunrin yii, Adeolu Bankọle, ẹni to jẹ aṣọ awọn ẹṣọ Sifu Difẹnsi lo n wọ jale pẹlu ibọn lọwọ.
Agbegbe Idagba, l’Ayetoro, lọwọ ti pada ba a lọjọ karun-un, oṣu keji, ọdun 2021 yii.
Awọn akẹkọọ kan nileewe Ọlabisi Ọnabanjọ Yunifasiti (Ayetoro Campus) ni wọn lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa, pe ole kan to wọṣọ Sifu difẹnsi waa ka awọn mọle pẹlu ibọn, o si gba foonu ati kọmputa agbeletan awọn lọ.
Ọga ọlọpaa ẹka Ayetoro, ACP Anthony Haruna, da awọn eeyan rẹ síta lati wa ọdaran to n faṣọ ìjọba jale ohun.
Lẹyin ọpọlọpọ ifimufinlẹ, awọn ọlọpaa mọbi ti afurasi naa n gbé, ile akọku kan ni. Nigba ti wọn wọnu ile ọhun, wọn ba apo kan ti foonu mẹfa wa ninu ẹ. Wọn ri kọmputa agbeletan kan, aṣọ Sifu difẹnsi meji ati ibọn ilewọ ibilẹ kan. Ṣugbọn wọn ko ri ẹni to n gbenu ile yii.
Ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ni ọkunrin kan yọ wọnu ile naa gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa ipínlẹ̀ ogun ṣe sọ. Ẹni to yọ wọle naa ni Adeolu Bankọle, bi wọn ṣe mu un nìyẹn, o di teṣan.
Foonu meji mi-in ti wọn lo ji pelu aago ọwọ lawọn ọlọpaa tun ba lọwọ rẹ.
Wọn ranṣẹ pe awọn to ja lole, bi wọn ti de ti wọn ri Adeolu ni wọn tọka ẹ pe ẹni to ja awọn lole ree.
Bakan naa ni iwadii fidi ẹ mulẹ pe Bankọle ji aṣọ Sifu to n wọ jale naa ni. Inu mọto Camry oṣiṣẹ ajọ naa kan lo ti ji i loṣu kejila, ọdun 2020, wọn si lo dana sun mọto yii lẹ́yìn to ko aṣọ naa ninu ẹ ni.
Ọfisa to ni aṣọ to n wọ yii naa ti fara han lọdọ awọn ọlọpaa, o ni yunifọọmu oun ni Bankọle n wọ jale kiri. CP Edward Ajogun ti ni ki wọn gbe e lọ sẹka