Monisọla Saka
Ọwọ palaba awọn afurasi meji kan ti wọn gbajumọ ninu jija awọn eeyan to ba fẹẹ gbowo nidii ẹrọ ATM banki lole ti ṣegi, lẹyin tawọn kan ka wọn mọbi ti wọn ti n ṣiṣẹ ibi wọn ọhun.
Awọn gende-kunrin mejeeji ọhun, Okwudili Solomon ati Ewelife Onyeka Fidelis, ni wọn ni ọjọ ti pẹ ti wọn ti n ṣe gbaju-ẹ fawọn eeyan ti wọn ba fẹẹ fi kaadi pelebe wọn gbowo nidii ẹrọ pọwopọwo ATM, niluu Abuja.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni ọwọ tẹ awọn ogbologboo ole yii nidii ATM banki kan l’Abuja.
Ninu fidio ti wọn gbe sori ẹrọ ayelujara ni ọkan ninu awọn tọrọ ṣoju wọn ti sọ pe niṣe lawọn ọkunrin naa maa n dibọn bii awọn sikiọriti banki. Latibẹ ni wọn yoo ti maa duro sẹyin awọn eeyan ti wọn waa gbowo, ti wọn yoo maa yọ wo kaadi wọn ati gbogbo nnkan ti wọn ba n tẹ.
Lọpọ igba, wọn yoo sun mọ awọn eeyan yii pe awọn fẹẹ ran wọn lọwọ lori ati-gbowo nidii ẹrọ yii. Ọgbọọgbọn ni awọn afurasi yii si fi maa n paarọ kaadi ATM mọ awọn eeyan naa lọwọ. Pupọ awọn ti wọn ti ṣe ni jamba latẹyinwa lo si ti n wa wọn, ko too di pe ilẹ mọ ba wọn lọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹfa, yii.
Lara nnkan ti wọn ba lara awọn afurasi yii ati ninu mọto ayọkẹlẹ wọn ni awọn ẹrọ igbowo POS ati ẹgba tawọn ti wọn n gun ẹṣin fi maa n tukọ rẹ.
Oriṣiiriṣii ẹlẹya ati iya ni wọn fi jẹ awọn eeyan yii. Bi wọn ṣe n lu wọn, bẹẹ ni wọn fi okun si wọn lọrun ati ẹsẹ bii ẹran, lẹyin naa ni wọn ni ki wọn duro sara ọkọ wọn lati ya fọto apapandodo, ki wọn too fa wọn le agbofinro lọwọ.
Awọn afurasi ọhun ti wa lakata awọn ọlọpaa.