Ẹ wo awọn ibeji yii, ale iya wọn ni wọn bimọ fun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Philomena ati Patricia Ukange lawọn obinrin meji to gbe ọmọ dani yii, ibeji ni wọn. Ki i ṣe pe wọn kere lati bimọ lo gbe wọn de oju iwe iroyin, ale iya wọn ni wọn bimọ fun ni.

Gẹgẹ bi iwe iroyin ‘The Nation’ to ṣiṣẹ iwadii ijinlẹ nipa iroyin naa ṣe sọ, ipinlẹ Nasarawa lawọn ọmọbinrin yii n gbe pẹlu iya wọn, Alice Ukange. Awọn Fulani to n dana sunle lo gbe wahala de ti wọn pa baba awọn ibeji yii, iyẹn lo gbe Alice atawọn ibeji de Lafia, ti wọn kuro nibi ti wọn n gbe tẹlẹ ki baba wọn too ku lojiji.

Nibi ti Iyaabeji ti n wa ọna atijẹ lo ti pade ọkunrin kan, Augustine Angwe, ọmọ ipinlẹ Benue. Iyawo Augustine yii naa ti ku ninu ijamba ọkọ pẹlu awọn ọmọ ẹ meji to bi. Oun ati Alice jọ n pade lọja ti obinrin yii ti n ra awọn ounjẹ tutu, to si n tun un ta, bi wọn ṣe bẹrẹ si i yan ara wọn lọrẹẹ ree, ti idunnu si tun pada sinu aye Iyaabeji lẹyin iku ọkọ ẹ.

Iyaabeji funra ẹ ṣalaye pe eeyan daadaa ni Augusitine nigba tawọn ṣẹṣẹ bẹrẹ, o ni bo ṣe n tọju oun lo n tọju awọn ibeji ti wọn ti pe ẹni ọdun mọkanlelogun. O n ran wọn nileewe, oun naa n fi tọwọ oun kun un, oun ko si mala pe ọkọ oun ti ku mọ.

Koda, oṣu kẹta lẹyin ti wọn bẹrẹ si i fẹra wọn ni  Iyaabeji ko lọ sile Augustine, ti wọn jọ n gbe bii tọkọ-taya.

Bi Augustine ṣe n tọju iya atawọn ọmọ yii lo tun ra foonu olowo nla fawọn ọmọbinrin naa, awọn ibeji yii si bẹrẹ si i fẹran rẹ, ifẹran to kọja jijẹ ale iya wọn.

Philomena to kọkọ ṣalaye bo ṣe bẹrẹ sọ pe oun mọ pe ale iya oun ni Augustine, ṣugbọn ọkunrin to rẹwa ti ko si ṣee wo lẹẹkan pere ni.

O loun ṣaa bẹrẹ si i fẹran ọkunrin naa, oun si n fi ifẹ han si i, bo ṣe pe oun lọjọ kan to wa nile ọti kan niyẹn, loun ba lọọ ba a nibẹ, lawọn ba jọ n ṣe faaji. O ni Augustine ko tiẹ kọkọ fẹẹ ba oun ṣere, ṣugbọn oun ṣaa lo tobinrin fun un titi tawọn fi wọ yara, lawọn ba ṣere ifẹ, latigba naa lo si ti di pe ti iya oun ko ba ti si nile bayii, to ba ọja rira lọ, oun ati Angwe  yoo maa mu nọmba ara awọn lọ ni. Kinni naa lo si pada ja soyun lọdun to kọja.

Patricia ko tiẹ fọrọ sabẹ ahọn sọ ni tiẹ, niṣe lo sọ pe oun ko mọ idi ti iya oun ṣe fẹran ọkunrin naa tẹlẹ, afi lọjọ akọkọ to ba oun sun ninu ile iya oun, ti kinni naa dun kọja awọn eyi toun ti n ṣe tẹlẹ, o ni lọjọ naa loun mọ pe bi Augustine ṣe rẹwa loju naa lo tun mọ kinni i ṣe daadaa.

Ọmọ naa ṣàlàyé fun akọroyin ‘The Nation pe, ‘’Diẹ lo ku ki iya mi tiẹ ka wa mọ lọjọ yẹn, nitori nibi ti mo ti n tun aṣọ mi ṣe lo ti de ba mi lojiji, laaarọ si ni. Iya mi beere pe kin ni mo n bọṣọ laaarọ kutu fun, mo si purọ fun un pe mo ṣẹṣẹ ra aṣọ naa ni, mo ni mo n wọ ọ wo ni ki n le mọ bo ṣe ri lara mi. Augustine wa ninu ileewẹ nigba yẹn, niya mi ba mu owo rẹ too waa mu nile, lo ba tun gba ọja lọ.

‘Bo ṣe lọ tan ni mo wọ Augustine jade pada, mo ni kinni rẹ dun, ko jẹ ka tun ṣe ẹẹkan si i, a si ṣe e.

Bo ṣe di nnkan ta a n ṣe lọ niyẹn titi ti mo fi loyun.’’

Augustine to fun wọn loyun ti mọ ohun to ṣẹlẹ, Alice tawọn ọmọ ẹ loyun ni ko mọ ẹni to ni oyun inu wọn. Iya naa loun beere lọwọ awọn ọmọ yii titi, wọn ko jẹwọ foun.

O ni ohun to kan ya oun lẹnu ni pe niṣe ni Augustine naa n sọ pe koun fi wọn silẹ, to ba ya wọn, wọn yoo jẹwọ.

Bẹẹ loyun awọn ibeji n dagba lai jẹwọ ẹni to loyun fun iya wọn, awọn mejeeji si mọ pe ale iya awọn lawọn jọ loyun fun.

Oṣu kin-in-ni, ọdun yii, ni Philomina bimọ obinrin, nigba ti Patricia bimọ ọkunrin loṣu kẹta. Lẹyin ti Patricia bi tiẹ ni aṣiri tu.

Augustine funra ẹ lo ji Iyaabeji ti wọn jọ sun loju oorun, o bẹrẹ alaye naa lodilodi, o si jẹwọ fun ale rẹ yii pe oun ni baba awọn ọmọ ti awọn ọmọ rẹ bi.

Ọkunrin yii kuku ṣalaye ara ẹ nigba ti ọrọ di ti mọlẹbi ọkọ Iyaabeji naa, bẹẹ naa lo si ṣe ṣalaye fun akọroyin iwe  iroyin ‘The Nation’ to ba sọrọ ni Nasarawa. O ni oun mọ pe ohun toun ṣe yii ko daa, eewọ ni. O ni awọn ibeji yii ni wọn gbe ara wọn waa ba oun, nigba ti wọn n ti ara wọn mọ oun lọrun loun ko ribi ti wọn si, bo ṣe di pe oun n ba wọn sun niyẹn toun si n ṣe kinni fun iya wọn naa lai jẹ ko mọ ohun to n lọ. Augustine loun tiẹ fẹẹ ṣẹyun naa fun wọn ṣugbọn wọn ko gba, wọn ni baba awọn ti kilọ fawọn ko too ku pe awọn ko gbọdọ ṣẹyun laye awọn, nitori ẹni to ba ṣẹyun yoo ku ni.

Ni bayii ṣa, o loun ko sọ pe oun yoo fẹ awọn ọmọ naa, ṣugbọn oun yoo gba awọn ọmọ ti wọn bi foun yii.

Augustine ni oun yoo maa ran Philomena ati Patricia nileewe, ki wọn pari iwe giga ti wọn n ka, wọn le lọọ fẹ ọkọ mi-in lẹyin igba yẹn.

Awọn ibeji naa lawọn ko ni i fẹ Augustine, ki iya awọn ma binu, gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii ṣeṣi ni o.

 

Leave a Reply