Ẹ wo awọn kọkọrọ ajẹbiidan ti Dosunmu fi maa n ji mọto gbe l’Abẹokuta

Faith Adebọla

 Iran awo-ṣe-haa ni fọto baba agbalagba kan, Alagba Sunday Dosunmu, ẹni ọdun mẹtalelaaadọta, ti ileeṣẹ ọlọpaa fi ṣọwọ s’ALAROYE lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ ọdun yii, pẹlu atẹjade kan, nibi ti baba naa ti na kọkọrọ agbelẹrọ meji kan soke, kọkọrọ naa jọra bii ojulowo kọkọrọ mọto ni ta a ba yọwọ ti igi ti wọn so mọ’dii wọn. Wọn ni ajẹbiidan lawọn kọkọrọ ọhun, tori ko si ilẹkun ọkọ ti wọn ko le ṣi. Baba ti wọn lo ṣẹṣẹ kuro lọgba ẹwọn yii mọ ọgbọn to maa n da si i.

Wọn ni to ba ti ṣakiyesi pe onimọto kan ko si nidii ọkọ rẹ fun igba pipẹ, niṣe ni jagunlabi yii yoo rọra lọ sidii ilẹkun ọkọ naa, apa ọwọ osi ni wọn lo maa n ba wọle, ti yoo si fi ayederu kọkọrọ ti wọn pe ni masita kii (master key) yii ṣi i, lai fu ẹnikẹni lara, koloju si too ṣẹju peu, ọkọ naa yoo ti dawati lẹsẹkẹsẹ, eyi ni iṣẹ adigunjale ti Alagba Dosunmu yii n ṣe tọwọ palaba rẹ fi segi.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, sọ ninu alaye rẹ nipa iṣẹlẹ yii pe lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022, lọwọ awọn ọlọpaa ẹka ileeṣẹ Kemta, ti kọkọ tẹ afurasi yii pẹlu iwa idigunjale, wọn ni ọkọ ayọkẹlẹ kan ti onimọto paaki jẹẹjẹ, lagbegbe Ọlọrunṣogo, nigboro Abẹokuta, loun atawọn ti wọn jọ n ṣiṣẹ oro naa fẹẹ ji gbe lọjọ ọhun to fi ko si pampẹ CSP Adeniyi Adekunle, to jẹ DPO teṣan Kemta.

Wọn wọ ọ dele-ẹjọ, adajọ si kọkọ la a mẹwọn, amọ o jọ pe igunpa lawọn agbofinro naa ti mu un, tori ko pẹ lẹyin ti igbẹjọ bẹrẹ, wọn tu Sunday Dosunmu silẹ pe ẹri tawọn ọlọpaa ko wa ko pọ to.

Ṣe Yooba bọ, wọn ni ba a gun ata lodo, ba a lọ ata lọlọ, iwa ata o le yipada, nnkan bii aago meje aabọ alẹ, ti okunkun ti bolẹ, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejila, oṣu Kẹjọ yii, lawọn ọdọ kan tun kẹẹfin Alagba Dosunmu laduubo Ẹlẹmẹ, nikọja NNPC, l’Abẹokuta. Ko mọ pe wọn n ṣọ oun, ni wọn ba ri i nibi to ti n pẹlẹngọ mọ mọto onimọto kan lẹgbẹẹ, o si n dọgbọn fi kọkọrọ buruku ọwọ ẹ ṣilẹkun ọkọ ọhun, o fẹẹ ji i gbe.

Bi ẹnikan ṣe pariwo, ‘ole’ bayii, niṣe lafurasi naa ki ere buruku mọlẹ, gigisẹ rẹ fẹrẹ kan an nipakọ, amọ ere meloo ni baba ẹni ọdun mẹtalelaaadọta yoo sa lẹgbẹẹ awọn ọdọ adugbo ti wọn san-an-gun ti wọn gba fi ya a, kia ni wọn ti gba a mu, ti wọn si ke sawọn ọlọpaa lati waa wo ohun to ṣẹlẹ.

Ibẹ ni wọn ti ba kọkọrọ agbelọrọ masita kii to fi n jale ọkọ ayọkẹlẹ kiri lara ẹ, oun naa si ti jẹwọ fawọn ọtẹlẹmuyẹ pe iṣẹ adigunjale loun n fi awọn kinni naa ṣe.

Ṣa, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Abiọdun Mustapha Alamutu, ti gbọ sọrọ yii, o si ti paṣẹ pe ki wọn ma tun fi ọrọ afurasi ọdaran yii falẹ mọ, o ni ki wọn tete taari ẹ siwaju adajọ, ko lọọ maa jẹ ‘ẹni lọ-lo bọ’ niwaju ofin lọhun-un.

Leave a Reply