Monisọla Saka
Obinrin ẹni ọdun mẹtalelogun (23) kan, Akinnowọnu Damilọla Victoria, to n ta oriṣiriṣii nnkan lori ẹrọ ayelujara ti ba ara ẹ ni teṣan ọlọpaa ipinlẹ Niger, nitori ẹsun jibiti ti wọn fi kan an.
Awọn eeyan to le ni ọgọrun-un, ni wọn ti ko sọwọ obinrin yii, ko si din ni miliọnu lọna aadọjọ Naira (150,000,000), to ti gba lọwọ wọn.
Nigba to n fidi ọrọ naa mulẹ niluu Minna, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ naa lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ keji, oṣu Kẹfa, ọdun yii, DSP Wasiu Abiọdun, ti i ṣe agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Niger, ṣalaye pe ẹsun gbaju-ẹ, aimu adehun ṣẹ pẹlu iwa ọdaran ati ẹsun ọdaran ori ẹrọ ayelujara ni kootu Majisireeti ilu Minna fi kan obinrin naa nigba ti wọn taari ọrọ rẹ sọdọ awọn lọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, odun 2023 yii.
O ni, “Lati kootu Majisireeti, ni wọn ti fi ọrọ obinrin ẹni ọdun mẹtalelogun kan to n jẹ Akinnọwọnu Damilọla Victoria, to n gbe ni Kọlawọle Street, Tunga, niluu Minna, nipinlẹ Niger, to wa leti.
Ni kete tọrọ naa de etiigbọ wa lawọn agbofinro ẹka ti wọn ti n ṣewadii ẹsun iwa ọdaran, State Criminal Investigation Department, SCID, bẹrẹ iṣẹ, ti wọn si pada ri afurasi ọhun mu, pẹlu iranlọwọ awọn mọlẹbi rẹ.
“Lasiko iwadii lo ṣalaye pe o ti to bii ọdun kan toun ti bẹrẹ iṣẹ òwò ori ayelujara nipasẹ ona kan toun ri lori opo ayelujara Facebook. O lawọn nnkan bii aṣọ obinrin, baagi, bata, foonu loniran-n-ran, kọmputa alagbeeletan atawọn nnkan eelo inu ile to n lo ina mọnamọna mi-in loun n ta.
‘‘Ọmọbinrin yii ni latara awọn aworan ọja toun n ta toun n gbe sori ayelujara faye ri yii loun fi ri awọn onibaara to pọ, ti wọn si maa n beere fun awọn ọja naa.
Damilọla ni nigba to ya lo di pe awọn onibaara oun maa n sọrọ nitori iye owo ọja oun, ati pe nigba to ya lo di pe k’oun sọ owo ọja silẹ patapata, tabi k’oun fi owo ọja ẹni kan ta fun ẹlomi-in”.
‘‘Ninu iwadii ta a ṣe nigba to di pe awọn eeyan pupọ ti sanwo ọja silẹ, ti ko si ri nnkan ti wọn sanwo fun gbe fun wọn, lo bẹrẹ si i parọ fun wọn pe awọn ẹṣọ aṣọbode, Kọsitọọmu (Customs), ti gba awọn ọja oun silẹ.
‘‘Yatọ si eyi, lojuna ati le mu kawọn eeyan nigbagbọ ati igbẹkẹle to jinlẹ ninu ẹ lọmọbinrin yii fi lọọ fi owo to le ni miliọnu meji Naira gba ile ikẹrusi nla nla meji sagbegbe Tunga ati Kpakungu, niluu Minna, eleyii lo tubọ lo lati ri iṣẹ jibiti rẹ ṣe daadaa’’.
Abiọdun tẹsiwaju pe nigba ti afurasi n sọ iye eeyan to ti kagbako ẹ, ati iye owo to ti ri lọwọ wọn, o lawọn eeyan to le ni ọgọrun-un lowo wọn wa lọwọ oun, toun jẹ ni gbese bii miliọnu lọna aadọjọ Naira. Mejilelaaadọrin ninu awọn to ti ṣe gbaju-ẹ fun ni wọn yọju si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadii iwa ọdaran niluu Minna, nibi tonikaluku ti n ṣe akọsilẹ nnkan to da wọn pọ, ati iye owo wọn to wa lọwọ obinrin naa fawọn ọlọpaa.
Bo tilẹ jẹ pe obinrin yii ṣe iforukọsilẹ ileeṣẹ okoowo rẹ lọdọ ileeṣẹ ijọba apapọ, Corporate Affairs Commission (CAC), leyii ti yoo mu ko rọrun fawọn eeyan lati ba iru ẹni bẹẹ dowo pọ lai foya pe owo awọn le wọgbo, sibẹ obinrin yii kowo wọn sa lọ.
Awọn ọlọpaa ni iwadii ti n lọ lori ọrọ naa, wọn ni awọn yoo foju afurasi bale-ẹjọ, ni kete ti iwadii ba ti tẹnu bepo.