Faith Adebọla, Eko
Ọlọrun lo mọ ibi tọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlogoji yii, David Ọmọruyi, ti ri kaadi idanimọ awọn ọlọpaa, tori kaadi naa lo loun fi n ko ara oun yọ lọwọ awọn agbofinro, ti wọn ko fi ri oun mu latọjọ yii, bẹẹ okoowo igbo tita atawọn egboogi oloro lo n ṣe l’Ekoo.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago mejila kọja iṣẹju diẹ loru ọjọ Aiku, Sannde, to lọ yii, lọwọ tẹ afurasi ọdaran yii pẹlu baagi kan to gbe sejika, bẹẹ ni wọn lawọn kan tẹle e, tawọn naa gbe oriṣiiriṣii baagi tawọn arinrin-ajo n kẹru si, dani
Bawọn ọlọpaa ṣe ri wọn laajin oru ni wọn da wọn duro, ṣugbọn kia ni David ti sọ fun wọn pe ara awọn agbonfinro loun, awo lo r’awo, tori ọlọpaa loun naa. O ni sajẹnti ọlọpaa loun, ara ikọ ọlọpaa Mopol 49 loun n ba ṣiṣẹ lagbegbe Ẹpẹ, nipinlẹ Eko, ati pe oun lawọn ọkunrin to gbe baagi naa n ba kẹru lọọ sile oun to wa ni Ojule kẹrin, Opopona Job, laduugbo Afromedia, Ọttọ-Awori.
Wọn ni ki wọn tiẹ too beere ami idanimọ ẹ gẹgẹ bii ọlọpaa lo ti fa kaadi idanimọ ọlọpaa yọ si wọn, kaadi ọlọpaa si ni loootọ pẹlu fọto pelebe ẹ rekete, ṣugbọn ara fu ọkan lara awọn ọlọpaa naa, o si beere pe ko si baagi ẹ fawọn kawọn wo ohun to wa ninu ẹ, n lakara ba tu sepo. Igbo rẹpẹtẹ lo kun inu awọn baagi ọhun fọfọ.
Bẹẹ lawọn to ku sọ baagi ọwọ wọn silẹ, ni wọn ba sa lọ, ṣugbọn David ko ribi sa lọ ni tiẹ.
Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro awọn ọlọpaa, sọ pe afurasi ọdaran yii ti wa lọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, ti wọn n wadii ọrọ wo lẹnu ẹ. Won lo ti jẹwọ pe oun ki i ṣe ọlọpaa rara, oun dọgbọn si i ni, tori koun le ribi ṣe okoowo egboogi oloro toun n ṣe lo mu koun da a bii ọgbọn.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki wọn wa awọn yooku ẹ to sa lọ naa lawari, o ni ayederu kaadi idanimọ tọkunrin yii n gbe kiri, ati baagi igbo ti wọn ba lọwọ ẹ, gbogbo ẹ lo maa sọ bo ṣe jẹ fun adajọ nigba to ba fara han lọhun-un.