Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Monday Alo lẹ n wo yii, ọmọ ipinlẹ Ebonyi to darapọ mọ ikọ adigunjale ni Ṣagamu, to fi hama lu awakọ kan lori, to si tun gbe mọto ẹ lọ.
Awọn ọlọpaa ni wọn ri Monday mu lalẹ ogunjọ, oṣu kọkanla yii, nigba ti ipe de ọdọ wọn ni teṣan Ṣagamu pe awọn adigunjale kan n dana lọwọ loju ọna Ṣagamu si Ikẹnnẹ, nipinlẹ Ogun.
DPO Ṣagamu, Okiki Agunbiade, ko awọn ọmọọṣẹ rẹ leyin, o di oju ija naa. Ṣugbọn bawọn ẹlẹgiri ọhun ṣe ri awọn ọlọpaa ni wọn bẹ sinu mọto Camry ti wọn ti ja gba tẹlẹ, ni wọn ba n sa lọ.
Ọna Interchange ni wọn gba gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ yii ṣe ṣalaye f’ALAROYE.
Awọn ọlọpaa naa gba ya wọn, nigba ti wọn si ri i pe ko fẹẹ sọna mi-in mọ ni wọn gbe mọto naa silẹ, wọn sa wọgbo lọ. Bi wọn ti wọgbo lọ lawọn ọlọpaa bẹrẹ si i wa wọn kiri, nibi ti wọn ti n dọdẹ wọn naa lọwọ ti ba Monday Alo pẹlu hama to fi fọ awakọ ti wọn gba mọto rẹ lori.
Lilu tawọn eeyan lu afurasi ole yii lagbara pupọ, awọn ọlọpaa lo gba a kalẹ, ti wọn si gbe e lọ sọsibitu fun itọju, ko ma baa ku. Bakan naa si ni wọn gbe onimọto to fi hama fọ lori naa lọ sileewosan pẹlu.
Ẹka itọpinpin ni CP Edward Ajogun ni ki wọn gbe Monday lọ fun ifọrọwanilẹnuwo si i, bẹẹ lo ni kawọn ọlọpaa wa awọn ẹgbẹ rẹ to sa lọ jade nibikibi ti wọn ba sa pamọ si.