Monisọla Saka
Oṣerebinrin ilẹ wa tawọn eeyan fẹran daadaa nni, Bimbọ Ademoye, to kopa ‘Arọlakẹ’ ninu sinnima Anikulapo, ni wọn fun lami-ẹyẹ oṣere-binrin alawada, adẹrin-inpoṣonu ti mùṣèmúṣè rẹ da múṣémúṣé ju lọ nibi eto tileeṣẹ amohunamworan African Magic gbe kalẹ, eyi ti wọn pe ni African Magic Viewers Choice Awards, (AMVCA), eyi to maa n waye lọdọọdun. Eto yii ni wọn gbe kalẹ lati fawọn oṣere, onkọtan, oludari ere atawọn mi-in bẹẹ lami-ẹyẹ fun iṣẹ takuntakun lọlọkan-o-jọkan ti wọn ṣe.
Nibi eto yii to waye lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Karun-un, ọdun yii, nileetura nla Eko Hotel and Suites, to wa lagbegbe Victoria Island, nipinlẹ Eko, ni wọn ti fami-ẹyẹ ẹni to ṣe daadaa ju lọ ninu ka paayan lẹrin-in, ipele tawọn obinrin, ninu awọn sinnima agbelewo, awọn ere ori tẹlifiṣan keekeeke atawọn ere atinuda mi-in ti wọn n gbe sori ẹrọ ayelujara da Bimbọ Ademoye, tawọn eeyan tun mọ si Iya Barakat tabi Selina lọla, nigba ti Brọda Shaggi gba tawọn ọkunrin.
Lọjọ Aiku Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni Bimbọ, to kundun ko maa pe ara ẹ lọmọ baba ẹ, gba ile ti baba ẹ n gbe laduugbo ti wọn bi oun gan-an alara si, to si ti ṣe kekere, Ebute-Mẹta, nipinlẹ Eko lọ, to si lọọ gbe ami-ẹyẹ olowo iyebiye ọhun le baba naa lọwọ lati fẹmi imoore rẹ han si i gẹgẹ bii nnkan iwuri fun gbogbo ilakaka ẹ lori aṣeyọri rẹ lẹnu iṣẹ tiata.
Lori opo ayelujara Instagram rẹ lo gbe fidio ibi to ti n gbe ami-ẹyẹ naa le baba ẹ lọwọ si. Ohun to kọ sabẹ fidio ọhun niyi, “Mo pada sile lati lọọ gbe ami-ẹyẹ ọhun fun baba mi. Alatilẹyin mi to ga ju, apata isadi mi, eegun ẹyin mi, baba mi. Mi o ba wọn ninu ile, ṣugbọn mo ti mọ’bi ti wọn maa wa. Wọn gbadun ki wọn maa ṣe faaji pẹlu awọn ọkunrin adugbo tọwọ wọn ba ti dilẹ lọjọ Sannde.
“Baba mi yii ni wọn gbe mi lọ sibi eto ti wọn ti maa n ṣayẹwọ fawọn oṣere nigba ti mo fẹẹ bẹrẹ tiata (audition). Odidi wakati mẹfa ni wọn fi duro lọjọ naa lọhun-un, titi ti mo fi ṣetan. Ṣe ẹ waa ri gbogbo awọn ara ti mo n da, to n pa yin lẹrin-in ninu awọn fiimu mi, inu adugbo yii naa lawọn eeyan ọhun ti wa. Latori Iya Barakat, titi de ori Todowede, to fi kan Selina, ibi ti mo ti mu gbogbo wọn ree, laduugbo wa yii ni imisi ọhun ti wa.
“Isinjẹ awọn kan laduugbo ni mo n ṣe lati ko gbogbo awọn ipa yẹn. Orukọ mi ni Bimbọ Ademoye. Ọmọ Ademoye Adekunle, Anti fun Ari, Ebute-Mẹtta ni mo si ti wa. Laduugbo yii ni wọn ti bi mi, ti mo dagba si. Ọpọlọpọ awọn eeyan lo wu mi lati fẹmi imoore han si, amọ mo n ṣiṣẹ lori ọrọ idupẹ mi lọwọ”.
Pẹlu inu didun, iwuri ati ẹrin ayọ ni Baba Bimbọ fi gbe ami-ẹyẹ ọmọ ẹ yii lọwọ.
Nibi ti baba ẹ atawọn eeyan ti n ṣe faaji, lo ti yọ kulẹ si wọn, to si gbe oriire to fi n wa baba naa kiri le e lọwọ.
Ko pẹ pupọ tawọn eeyan fi n pọ si i laarin ibẹ, ti wọn n ṣajọyọ pẹlu baba atọmọ naa.
Bakan naa ni Bimbọ tun dupẹ lọwọ awọn alatilẹyin atawọn ololufẹ ẹ, o ni, “Si gbogbo awọn eeyan ti wọn duro fun mi, ti wọn n ti mi lẹyin, ti wọn si n jade lati kun mi lọwọ, ọpẹ adaadatan ni mo ni ọpẹ mi fun yin.
Fawọn temi pàtàkì pátákí lori ẹrọ ayelujara kaakiri, mi o mọ bi gbogbo yin ṣe parapọ di ẹbi mi, ṣugbọn mo fẹẹ bẹẹ, o dun mọ mi. Mo dupẹ aduroti gbogbo yin pata”.
Bayii ni Bimbọ dupẹ lọwọ awọn eeyan, agbegbe Ebute-Mẹtta ti irinajo rẹ ti bẹrẹ, to si tun jẹ orisun imisi fun un, ati ni pataki julọ, baba ẹ to ni oun gan-an ni ẹni to n ṣatilẹyin ati koriya foun ju lọjọkọjọ.