Ẹ wo ọmọ iya meta ti wọn n digunjale n’Ijẹbu

Gbenga Amos, Ogun

Loootọ ni wọn maa n sọ pe ọmọọya mẹta ki i rewele, ṣugbọn ọrọ yii ko ṣiṣẹ lọdọ awọn ọmọọya mẹta kan lagbegbe Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun o, ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ wọn, iṣẹ adigunjale lawọn mẹtẹẹta, atọrẹ kan to ṣikẹrin wọn, n ṣe.

Hammed Jagbojagbo, Idris Jagbojagbo ati Tobi Jagbojagbo tawọn mẹtẹẹta jẹ tẹgbọn-taburo, ati Tosin Ogundẹkọ, lọwọ palaba wọn ṣegi nigba ti wọn lọọ jale ni ṣọọbu ti wọn ti n ta tẹtẹ Baba Ijẹbu kan to wa laduugbo Odi-Olowo, n’Ijẹbu-Ode, wọn ko ẹgbẹrun lọna aadọrun-un Naira (N90,000), wọn si tun ji ọkada Bajaj to jẹ ti Ọgbẹni Clement Conleth, lọ.

Ninu alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe ninu atẹjade to fi sọwọ s’ALAROYE lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹwaa yii, o ni gẹrẹ tawọn firi nidii ọkẹ alọ-kolohun-kigbe ẹda naa ṣiṣẹẹbi wọn tan lawọn aladuugbo kegbajare wa si teṣan ọlọpaa Igbeba, oju-ẹsẹ si DPO teṣan naa, CSP Musiliu Doga, atawọn ọmọọṣẹ ẹ ti lọ sibẹ, wọn gba, fi ya awọn adigunjale naa, wọn le wọn gidi.

Nigbẹyin wọn ri ọkan ninu wọn mu, Tosin Ogundẹkọ, tori oun lo gun Bajaj ti wọn ji ọhun, atoun ati alupupu ọhun dero ahamọ.

Tosin yii lo juwe ibi ti wọn ti le mu awọn yooku ẹ, o ni Ẹpẹ lawọn ọmọ Jagbojagbo mẹtẹẹta tawọn jọ n digun jale n gbe, bo si ṣe juwe ni wọn ba wọn, ti wọn si mu wọn.

Alukoro ni ẹnikan tun wa toun naa n jẹ Tosin, ṣugbọn sọkẹẹti (socket) lorukọ inagijẹ ẹ, wọn jọ n jale ni, bo tilẹ jẹ pe o ti sa lọ.

Wọn lawọn afurasi yii jẹwọ pe o ti pẹ tawọn ti n jale, ọkada lawọn saaba maa n ja gba, Ẹpẹ lawọn n gbe, ṣugbọn Ijẹbu-Ode ati ayika rẹ lawọn ti n ṣiṣẹẹbi naa, awọn si maa n lu ọkada tawọn ba ji gbe ta ni gbanjo ni.

Lara ẹru ofin ti wọn ka mọ wọn lọwọ nigba ti wọn lọọ yẹle wọn wo ni ibọn agbelerọ pompo kan ati ọkada Bajaj kan.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti ni ki wọn tọpasẹ Tosin to sa lọ, ki wọn si wa a lawaari. O ni tawọn ọtẹlẹmuyẹ ba ti pari iṣẹ iwadii, awọn maa sin gbogbo wọn dewaju adajọ, ki wọn le gba sẹria to tọ si wọn.

Leave a Reply