Faith Adebọla, Eko
Bi ko ba si ọpẹlọpẹ awọn ero to fẹẹ wọ mọto ni Ibudokọ Orile, nitosi ileepo Ọdun-Ade, lagbegbe Surulere, l’Ekoo, ti wọn gburoo igbe ọmọ jojolo kan ninu igbo ti wọn ju u si, boya ibẹ lọmọ oṣu kan ọhun iba ku si.
Ko sẹni to le sọ pato igba tọmọ naa de ibi ti wọn ti ri i yii, wọn lo jọ pe idaji ọjọ Ẹti, Furaidee, niya ọmọ naa ti lọọ gbe e ju sinu igbo ṣuuru kan to wa nitosi ibudokọ naa, nnkan bii aago mẹjọ aarọ tawọn ero fẹẹ wọ mọto ni wọn bẹrẹ si i gbọ igbe ọmọ jojolo, wọn si ṣakiyesi pe ko sẹni to pọn ọmọ laarin wọn.
Wọn lawọn ero yii ni wọn fimu finlẹ, ni wọn ba ri ọmọ ọhun nibi ti wọn yọọ sọnu si, wọn si tẹ teṣan ọlọpaa Orile Iganmu laago.
Oju-ẹsẹ lawọn ọlọpaa ti debi iṣẹlẹ naa, wọn gbe ikoko naa, wọn si fi i ṣọwọ si Kọmiṣanna wọn, Hakeem Odumosu, ni Ikẹja.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa Eko, CSP Olumuyiwa Adejọbi, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ f’ALAROYE sọ pe kọmiṣanna ti ni ki wọn gbe ọmọ ọhun lọ sile itọju awọn ogo wẹẹrẹ tijọba, ki wọn le fọmọ naa ni itọju to peye, ibẹ si lọmọ naa wa bayii.
Kọmiṣanna parọwa sawọn obi lati jawọ ninu iwa ọdaju bii eyi, ati pe ẹnikẹni tọwọ awọn ba tẹ nidii aṣakaṣa ọhun maa ri pipọn oju ijọba.