Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ayederu dokita kan, Rabiu Ọlalekan, lọwọ palaba rẹ ṣegi pẹlu bi ọwọ awọn agbofinro ṣe tẹ ẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ogunjọ, oṣu Kejila, ọsẹ yii.
Rabiu to jẹ oludasilẹ ile-iwosan aladaani kan to porukọ rẹ ni Iremide, eyi to wa lagbegbe Orita-Ojo, niluu Odigbo, lọwọ tẹ lẹyin to ṣiṣẹ abẹ fun alaboyun kan ta a forukọ bo laṣiiri.
Lẹyin to ṣiṣẹ abẹ ọhun tan lẹjẹ bẹrẹ si i da ṣuruṣuru lati oju ara obinrin naa, leyii to mu ki ọkọ rẹ sare gbe e lọ si ọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun Fasiti ipinlẹ Ondo to wa loju ọna Lájé, niluu Ondo.
Ileewosan ọhun lawọn dokita ti ṣalaye fun ọkọ rẹ pe ẹjẹ to n da lara iyawo rẹ ko sẹyin bi ayederu dokita to ṣiṣẹ abẹ fun un ṣe ran ile-ọmọ ati ile-itọ rẹ pọ mọ ara wọn eyi ti ko yẹ ko ri bẹẹ.
Wọn fi iṣẹlẹ yii to awọn ọlọpaa leti, latibẹ ni wọn si ti ṣeto bi wọn ṣe lọọ fi pampẹ ofin gbe Rabiu ninu ọsibitu rẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Oyeyẹmi Oyediran, ni ohun ti awọn fidi rẹ mulẹ lasiko ti awọn n fọrọ wa ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn naa lẹnu wo ni pe ki i ṣe ojulowo dokita.
Ileewe eleto ilera kan to wa niluu Ijẹbu-Ode, ni Rabiu lọ, nibi to ti lọọ kẹkọọ nipa eto ilera alabọọde, o ni ṣe lo kan n tan awọn eeyan jẹ pẹlu bo ṣe n pe ara rẹ ni dokita.
Ninu ọrọ tirẹ, Rabiu ni oun ṣiṣẹ abẹ fun obinrin naa loootọ, bẹẹ ni ki i ṣe oun lẹni akọkọ ti oun yoo ṣiṣẹ abẹ fun latigba toun ti da ọsibitu naa silẹ.
O ni oun ṣe iṣẹ naa daadaa, o si ti to bii ọjọ mẹwaa lẹyin ti oun ti ṣiṣẹ abẹ naa tan ki ọrọ ẹjẹ to n ya jade lati oju ara rẹ too waye.
O ni ko sohun meji to ṣokunfa iṣun ẹjẹ naa ju kikọ ti oun ati ọkọ rẹ kọ lati ra oogun to yẹ ko lo lọ.