Gbenga Amos, Ogun
Okoowo buruku lawọn tọkọ-taya yii, Godday Samuel ati Ebere Samuel, n fi n ṣọla l’Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, kọwọ palaba wọn too segi laipẹ yii. Niṣe ni wọn n ji ọmọọlọ gbe nigboro, ti wọn si n fi wọn ṣọwọ sorileede Burkina Fasso, fun owo ẹru.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, lo ṣiṣọ loju eegun ọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, ninu atẹjade kan to fi sọwọ s’ALAROYE. O ni ọjọ kẹtadinlogun, oṣu naa, lọwọ ba Godday ati Ebere, lẹyin ti wọn ti ji ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan, Maria Adeniji, gbe.
Baba Maria, Ọgbẹni Okikiolu Adeniji, lo kegbajare lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa niluu Atan-Ọta, lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, pe ki wọn gba oun, ki wọn ma jẹ koun foju sunkun ọmọ, ṣadeede lawọn o ri Maria nile, ọmọ oun o si ki i rinrinkurin, o lawọn ti wa a titi, awọn o mọ’bi tawọn tun le wa a si, bẹẹ ọmọ ẹni ku san ju ọmọ ẹni sọnu lọ.
Eyi lo mu kawọn ọlọpaa, atawọn aladuugbo kan gbe igbimọ dide lati wa gbogbo kọrọ kọlọfin ibi to ṣee ṣe kọmọbinrin naa jẹ si. Nibi ti wọn si ti n beere ẹ nibi ti wọn ti kẹẹfin ẹ kẹyin ko too dawati, ni wọn ti ta wọn lolobo pe o jọ pe awọn ri ọmọbinrin ọhun pẹlu Ebere, iyẹn iyawo Godday, laṣaalẹ ọjọ to sọnu naa.
Kia lawọn ọlọpaa ti ke si Ebere pe ko sọ ohun to mọ nipa iṣẹlẹ naa fawọn, ṣugbọn niṣe lobinrin yii ni oun o tiẹ gbooorun ẹni ti wọn n wa ọhun rara, debi toun maa ri i soju, o nirọ lawọn ti wọn lawọn ri i pẹlu oun n pa, ko sohun toun fẹẹ fọmọọlọmọ ṣe.
Ṣa, awọn ọlọpaa da a duro si teṣan, wọn si pe ọkọ ẹ lori aago pe ko yọju sawọn, iyawo ẹ ti wa lọdọ awọn.
Nigba ti Godday de, ọrọ rẹ ko ba tiyawo ẹ dọgba, afurasi naa jẹwọ pe loootọ lawọn ri Maria, ọdọ awọn lo sun lalẹ ọjọ ti wọn n wa a mọju, ati pe idaji ọjọ keji lawọn ti fọmọbinrin naa ṣọwọ si Eko, tori ibẹ ni wọn ti maa di i mẹru lọ si orileede Burkina Fasso, wọn lawọn kọsitọma wọn kan ti n duro de e lọhun-un, yoo maa ṣiṣẹ ọmọọdọ, awọn yoo si maa ba a gbowo iṣẹ ẹ tọju pamọ, titi digba to ba fẹẹ pada wale.
Wọn ni iwadii fihan pe ọmọ tuntun ki i ṣe akọpa ajẹ, awọn afurasi yii ti wa lẹnu owo jiji ọmọ gbe ati fifi ọmọ ọlọmọ ṣowo ẹru yii tipẹ, awọn alajọṣe wọn kan ni wọn n ba ṣiṣe lorileede Burkina Fasso.
Ṣa, kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti paṣẹ kawọn ọtẹlẹmuyẹ lẹka ti wọn ti n gbogun ti fifeeyan ṣowo ẹru nipinlẹ Ogun, lolu-ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Eleweẹran, Abẹokuta, tubọ ṣewadii to lọọrin lori iṣẹlẹ yii.
Lẹyin iwadii, wọn ni Misita ati Misiisi Samuel yii maa kawọn pọyin rojọ niwaju adajọ.