Ẹ wo wọn o, Mọsuru atawọn ẹgbẹ ẹ ti wọn dumbu iyaale ile ati ọlọkada bii ẹran l’Ado-Odo

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta

Awọn ọkunrin marun-un yii leeyan ko ba maa pe ni apani-ma-yọda, nitori ka ni ki i ṣe pe wọn fẹnu ara wọn jẹwọ pe awọn lawọn dumbu iyawo oniyawo torukọ ẹ n jẹ Memunat Akinde ati ọlọkada kan torukọ tiẹ n jẹ Ibikunle Ajọsẹ ni, ko sẹni to yoo mọ pe awọn ni wọn ṣiṣẹ ibi naa lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun 2020, ti wọn deede dawati.

Jẹẹjẹ ni Memunat to n ta ẹja fẹẹ lọọ ra ọja rẹ lọja Idoleyin, l’Ado-Odo, Ibikunle Ajọsẹ ni ọlọkada to gbe e lọjọ naa, afi bo ṣe jẹ alọ awọn mejeeji lawọn ẹbi wọn ri, ti wọn ko ri abọ wọn.

Ọkọ Memuna lo lọọ fi to wọn léti lẹka olu ileeṣẹ ọlọpaa to wa l’Ado -Odò pe oun ko ri iyawo oun to lọ sójà lati ọjọ akọkọ ninu oṣu kẹwaa mọ, bawọn ọlọpaa ṣe bẹrẹ iṣẹ abẹnu ti wọn yoo fi ri obinrin ẹni ọdun marundinlaaadọta (45) naa niyẹn pẹlu ọlọkada ti wọn jọ dawati.

Ọkan ninu awọn marun-un yii lọwọ kọkọ ba, Okediran Mọnsuru lo n jẹ, Badagry ni wọn ti ri i mu gẹgẹ bi DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe wi.

Monsuru ti wọn ri mu lo ṣokunfa bi ọwọ ṣe ba Ajaoba Monday, Akewusola Wajud ati Nupo Pona.

Àwọn mẹrẹẹrin jẹwọ pe ọkunrin ogbologboo ajagungbalẹ kan ti wọn n pe ni Lebo lawọn n ṣiṣẹ fun.

Wọn ni awọn lawọn da Memuna ati Ibikunle lọna labule Abisoye, awọn gbe wọn wọnu ile akọku kan ninu igbo, awọn so wọn lọwọ atẹsẹ, awọn si pe Lebo lori foonu pe ọwọ awọn ti ba ẹran meji o.

Wọn ni nigba ti Lebo de, o paṣẹ pe kawọn dumbu awọn eeyan meji yii.

Nigba naa ni Okediran Mọnsuru, Ajaoba Monday ati  Akewuṣọla Wajud di awọn ti wọn fẹẹ pa naa mu,  Nupo Pona si fi ada mimu kan dumbu wọn bii ẹran!

Wọn ni bawọn ṣe pa wọn tan lawọn pe afurasi karun-un, iyẹn Dasu Sunday, to jẹ babalawo.

Bi Sunday ṣe de ni gbogbo wọn kun ẹran ara Memuna ati Ibikunle, wọn ṣa wọn si wẹwẹ, wọn si ko ẹran awọn eeyan tawọn araale wọn n wa naa sinu apo, Sunday Babalawo si gbe e lọ sibi ti yoo ti sọ wọn di ètùtù oogun owo.

Ojubọ ti Sunday ti n ṣoro ẹ ni awọn ọlọpaa ti pada ri ori Memuna, wọn si ni gbogbo awọn to ṣiṣẹ yii ti wa latimọle, afi Lebo, olori wọn nìkan, lọwọ ko ti i ba, ti wọn n wa a gidigidi.

 

 

Awọn to wa latimọle yii ko ni i pẹẹ de kootu fun ijẹjọ, gẹgẹ bi CP Edward Awolọwọ Ajogun ti paṣẹ.

Leave a Reply