Ẹ woju awọn baale ile ti wọn n ṣẹgbẹ okunkun tọwọ ba l’Ogun

Faith Adebọla

 Baale ile ni gbogbo wọn, ko si sẹni tọjọ ori ẹ din si ọgbọn ọdun laarin awọn maraarun, amọ lasiko yii, wọn o si lọdọ lọọdẹ wọn, wọn o si si lọdọ awọn mọlẹbi wọn, tori ahamọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun ni wọn wa, ẹsun ti wọn si fi kan wọn ni pe wọn n ṣe ẹgbẹ okunkun tofin ti ka leewọ, wọn si tun ṣe ẹnikan to fẹẹ taṣiiri wọn leṣe.

Orukọ awọn afurasi ọdaran maraarun ni Ismaila Adetayọ, ẹni ọdun mejilelogoji, oun lo dagba ju laarin wọn, Kunle Oluwọle, ẹni odun mẹtadinlogoji, Dare Kẹhinde, ẹni ọdun marundinlogoji, Ibrahim Adenmọṣun ati Meshach Ọlaide tawọn mejeeji jẹ ẹni ọdun mọkanlelọgbọn.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla, sọ ninu atẹjade kan to fi sọwọ s’ALAROYE lori ẹrọ ayelujara, lọjọ kẹsan-an oṣu Kẹjọ yii pe awọn afurasi yii ni wọn n yọ awọn olugbe Aboro lẹnu, wọn ni wọn ti jẹwọ pe awọn lawọn wa nidi ipaniyan ati iwa janduku to n ṣẹlẹ lagbegbe naa.

Oriṣiiriṣii ipe idagiri tawọn araalu fi ṣọwọ sileeṣẹ ọlọpaa lo mu ki CSP Isaac Adekune Awoniyi, to jẹ DPO ẹka teṣan Matọgun, ko awọn ọmọọṣẹ ẹ sodi, wọn finmu finlẹ daadaa, awọn ẹṣọ alaabo adugbo kan si tun kun wọn lọwọ, eyi lo jẹ kọwọ ba awọn afurasi yii nibi ti wọn sa pamọ si.

Wọn lawọn afurasi ọdaran yii ṣakọlu si ọkunrin kan, Ogwu Uzoma, nigba tiyẹn ko sakolo wọn, wọn si tun halẹ mọ ọn pe niṣe lawọn maa pa a danu bi ko ba ko tiransifaa gbogbo owo to wa ninu akaunti banki rẹ fawọn.

Ibi ti wọn ṣe ọkunrin naa leṣe si lawọn ọlọpaa n sare lọ, pe ki wọn le doola ẹmi ẹ, aṣe awọn jagunlabi yii wa nitosi, wọn si tun ṣakọlu sawọn ọlọpaa naa, ko too di pe ọwọ tẹ wọn nigbẹyin, bo tilẹ jẹ pe awọn kan lara wọn sa lọ.

A gbọ pe wọn ti gbe Uzoma lọọ ọsibitu Ayọdele, to wa ni Matọgun, nibi ti wọn ti n ṣetọju rẹ lọwọ.

Lara nnkan ija ti wọn ka mọ awọn afurasi tọwọ ba yii ba yii lọwọ ni akufọ igo, ada loriṣiiriṣii, ọbẹ, ati egboogi oloro to pọ, wọn ni igbo ni kinni naa, oun ni wọn n fa sagbari ti wọn fi n ṣiṣẹẹbi. Iwadii ti tun fi han pe ọmọ ẹgbẹ okunkun ‘Aiye’ ni wọn, wọn si ti jẹwọ pawọn lawọn maa n ṣakọlu sawọn oṣiṣẹ ti wọn lọọ ibiiṣẹ wọn laarọ atawọn to n dari bọ lati ibiiṣẹ lalaalẹ, ti wọn si n ja wọn lole owo ati dukia wọn.

Iwadii ṣi n tẹsiwaju lori iṣẹlẹ yii, bi Alukoro ṣe wi. O lawọn maa foju wọn bale-ẹjọ laipẹ tiwadii ba ti pari.

Leave a Reply