Ẹ woju minisita ilẹ wa yii, biliọnu mejilelogun lo ko jẹ

Adewale Adeoye

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ ati  ṣiṣe owo ilu mọku-mọku lorileede yii, Economic And Financial Crimes Commision (EFCC) ti bẹrẹ iwadii nipa ẹsun ikowojẹ ti wọn fi kan minisita fọrọ ina mọna-mọna lorileede yii tẹle, Alhaji Sale Mamman. Bakan naa ni won sọ pe gbara tawọn ba ti pari gbogbo iwadii awọn tan nipa ẹsun ọhun lawọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ lati le fimu kata ofin.

ALAROYE gbọ pe laarọ kutukutu Ọjọruu, jo Wesidee, ọjọ Kewaa, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, ni Alhaji Sale de si ọfiisi ajọ naa, lẹyin ti wọn fiwe pe e pe ko waa sọ tẹnu rẹ lori ẹsun ikowojẹ oni biliọnu mejilelogun (N22B) ti wọn fi kan an.

Wọn fọwọ ofin mu mi isura tẹlẹ naa latari iwadii pataki kan ti ajọ naa n ṣe lọwọ lori owo tabua kan ti wọn lo poora lakooko ti ọkunrin naa fi wa nipo gẹgẹ bíi minisita.

Gbara to de si ọfiisi ajọ naa to wa niluu Abuja, ni wọn ti bẹrẹ si i lọ ọ nifun daadaa, ki wọn le mọ ọna ẹru ti owo ọhun gba jade lapo ijọba ilẹ yii.

A gbọ pe ṣe ni Alhaji Sale lẹdi apo pẹlu awọn ọga kọọkan lẹnu ileeṣẹ ọhun, ti wọn si ji owo to yẹ ki wọn fi ṣiṣe ina Zungeru ati Mambilla Hydro Project, ti wọn si pin in laarin ara wọn.

Ṣa o, ALAROYE gbọ pe awọn dukia bii: ile, ilẹ pẹlu mọto olowo nla gbogbo ti Alhaji Sale fi owo to ri nibi iwa ole naa ra pata lajọ EFCC ti ṣẹwadii nipa wọn, ti wọn si ti mọ ibi tawọn dukia naa wa pata bayii. Bakan naa ni gbogbo owo ilẹ okeere ati tilẹ yii pata ti wọn ri ninu akanti rẹ ni wọn ti n gba pada diẹdiẹ bayii.

 

Leave a Reply