Faith Adebọla
Ọja igbalode kan to gbajumọ bii iṣana ẹlẹẹta l’Abẹokuta, nibi ti wọn ti n ta awọn foonu, kọmputa, atawọn eroja rẹ loriṣiiriṣii, eyi to wa lagbegbe Oke-Ilewo, lawọn afurasi adigunjale kan doju sọ laṣaalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ti wọn lọọ fọ ọ. Niṣe ni wọn ṣina ibọn bolẹ lojiji, wọn fọ ṣọọbu awọn ẹni-ẹlẹni to n taja nibẹ, wọn si ji awọn dukia ati ọja wọn ko, ṣugbọn ọwọ tẹ ọkan ninu wọn, Ṣakiru Adeniji, ẹni ọdun mejilelọgbọn.
Ninu alaye ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe ninu atẹjade kan to fi ṣọwọ s’ALAROYE l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ keji iṣẹlẹ ọhun, o ni ni nnkan bii aago marun-un aabọ irọlẹ, nigba tawọn ontaja kan ti n palẹ ọja wọn mọ lati ṣiwọ kara-kata ọjọ naa, tawọn mi-in si ti lọ sile wọn, lawọn janduku kan ya bo apa kan ọja ọhun, nibi ti wọn n pe ni Tarmac, niṣe ni wọn ṣina ibọn bolẹ. Iro ibọn tawọn eeyan ibẹ gbọ ko jinnijinni ba wọn, awọn kan sa asala fẹmii wọn lai duro tilẹkun ṣọọbu, nigba tawọn kan sare doju bolẹ, eyi lo si fawọn alọ-kolohun-kigbe ẹda naa laaye lati ji wọn lẹru ko.
Amọ, awọn kan fi ipe idagiri ṣọwọ sori aago ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Ibara, eyi ti ko jinna pupọ sibi tiṣẹlẹ ọhun ti waye. Wọn ni lọgan ni DPO teṣan naa, CSP Abayọmi Adeniji, ti paṣẹ fawọn ọmọọṣẹ rẹ lati lọọ gbeja awọn ti wọn n ja lole ọhun. Awọn ẹṣọ Amọtẹkun kan tawọn naa ti gbọ siṣẹlẹ ọhun si kun wọn lọwọ pẹlu.
Nigba ti wọn debẹ, kaka kawọn ẹlẹgiri yii sa, niṣe ni wọn doju ibọn kọ awọn ọlọpaa, niro ati eruku ibọn ba gba gbogbo ibẹ kan. Nibi tọta ibọn ti n fo lau lau kiri lawọn ole ọhun ti yinbọn mọ ọkan ninu awọn ontaja Tarmac ọhun nibi to fori pamọ si, o si ṣubu lulẹ loju-ẹsẹ, o ku patapata.
Nigba tawọn afurasi yii ri i pe ọwọ awọn ọlọpaa ro ju tiwọn lọ, wọn mi sẹyin, wọn si bẹrẹ si i juba ehoro lọkọọkan, wọn sa lọ.
Awọn agbofinro naa gba, wọn fi ya wọn, eyi lo si mu kọwọ wọn tẹ Ṣakiru. Lara nnkan ija ti wọn ri gba lọwọ ẹ ni ibọn agbelẹrọ oloju-meji kan, awọn oogun abẹnugọngọ to so mọra jiganjigan, ati ọta ibọn.
AIG Frank Mba, to ṣẹṣẹ gba igbega kuro nipo Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun bayii, ti paṣẹ pe ki wọn taari jagunlabi sọdọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ti wọn n ṣewadii iwa ọdaran, ki wọn le tubọ ri okodoro iwakiwa ọwọ wọn. Bakan naa lo paṣẹ fawọn ọlọpaa pe awari tobinrin n wa nnkan ọbẹ ni ki wọn fọrọ awọn afurasi yooku ti wọn sa lọ ṣe, bo tilẹ jẹ pe ọpọ ninu wọn ni wọn ti fara kona ibọn, sibẹ, o ni ki wọn wa wọn ri, ki wọn si ba wọn ṣẹjọ lẹyin iwadii.
Latari eyi, Mba rọ gbogbo araalu pe ki wọn tete ta ileeṣẹ ọlọpaa to ba wa nitosi lolobo nigbakuugba ti wọn ba ri ẹnikẹni to n tọju ọgbẹ ibọn, tori o le jẹ ọkan lara awọn ẹlẹgiri t’ọta ba ọhun ni.