Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ayederu sọja kan, Lawal Taiwo, lọwọ awọn agbofinro tẹ niluu Okitipupa lọsẹ to kọja.
ALAROYE gbọ pe adugbo Togbe, lagbegbe Agege, ni Taiwo n gbe l’Ekoo. Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, lọwọ awọn ọmọ ogun ti wọn ṣẹṣẹ ko lọ si agbegbe Okitipupa fun akanṣe iṣẹ tẹ ẹ pẹlu aṣọ sọja tuntun lọrun rẹ.
Afurasi ọdaran ọhun lọwọ palaba rẹ ṣegi lasiko to waa fi ara rẹ han afẹsọna rẹ to n gbe l’Okitipupa gẹgẹ bii ọkan ninu awọn ṣọja Naijiria.
Ninu ifọrọwerọ ta a ṣe pẹlu rẹ, alaye to ṣe fun wa ni pe oun ki i jale, bẹẹ ni ko sẹni ti oun fiya jẹ lọna aitọ ri latigba toun ti n dibọn bii sọja.
O ni ọjọ pẹ ti iṣẹ naa ti n wu oun lati ṣe, ṣugbọn ti wọn ki i mu oun nigbakuugba ti wọn ba n ṣeto igbani ṣiṣẹ ologun.
Nigba to si ti gbiyanju titi ṣugbọn ti ko rẹni ran an lọwọ lo pinnu ati lọọ ge aṣọ ati bata awọn ṣọja funra rẹ, èyí tó ń wọ kiri kawọn eeyan le ro pe ọkan ninu awọn sọja Naijiria ni.
Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Ọdunlami Funmi, ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori ẹsun ti wọn fi kan Taiwo, o ni ayederu ṣọja naa ko ni i pẹ foju bale-ẹjọ lẹyin ti iwadii ba ti pari lori ọrọ rẹ.