Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti gboṣuba fun oniruuru iṣẹ takuntakun ti Aarẹ Muhamọdu Buhari n ṣe lori idagbasoke awọn nnkan amayedẹrun lorileede yii.
Ninu atẹjade kan ti Akọwe iroyin Oluwoo, Alli Ibrahim, fi sita ni kabiesi ti sọ pe igbesẹ igbogunti iwa ibajẹ to n lọ lọwọ lorileede yii fi han pe ẹni ti ko faaye silẹ fun iwa ibajẹ ni Aarẹ.
Oluwoo, ẹni to ṣapejuwe Buhari gẹgẹ bii adari to jẹ olotitọ ati olododo ninu itan orileede Naijiria, sọ pe oun ko le gbagbe aarẹ naa laelae.
O ni, “Buhari ki i ṣe onijagidijagan eeyan. Mi o mọ pe ọkọ reluwee to gbounjẹ fẹgbẹ gbawo bọ le ṣiṣẹ lorileede yii, iyanu tun ni atunṣe oju-ọna Eko si Ibadan tun jẹ fun mi. Mi o le gbagbe Buhari rara.
“Fun igba akọkọ laarin nnkan bii ogun ọdun, eeyan le wa mọto laarin Eko si Ibadan lai si sun-kẹrẹ-fa-kẹrẹ ọkọ, olotitọ eeyan nikan lo le ṣe eleyii lai ri ibinu awọn alagbara lorileede yii.”
Ọba Akanbi sọ siwaju pe awọn to ti dari orileede yii sẹyin ni wọn ṣokunfa bi awọn nnkan amayedẹrun ṣe bajẹ, o ni ko si eyi to gbe igbesẹ akin ti Buhari gbe lori ọrọ idagbasoke orileede yii lara wọn.
Oluwoo ni ọrọ eto iṣuna to dẹnukọlẹ ati eto aabo to mẹhẹ bayii jẹ eyi ti iṣejọba Buhari jogun ba latọdọ awọn to ti ṣejọba sẹyin, ṣe lo si yẹ ki awọn ọmọ orileede yii maa gboṣuba fun Aarẹ lori igbesẹ rẹ nipa ọrọ iwa ibajẹ.
Oluwoo waa ke si gbogbo awọn adari lẹlẹkajẹka lati ṣawokọṣe Aarẹ Buhari, ki wọn ma ṣe faaye gba iwa jẹgudujẹra. O si tun rọ awọn araalu lati dẹkun bibu ẹnu atẹ lu aṣeyọri iṣejọba Aarẹ Buhari.