Adewale Adeoye
O le daadaa ni igba (200) awọn onibaara ti awọn alaṣẹ ijọba ilu Abuja lọhun ko gbogbo wọn sinu mọto akero nla kan, ti wọn si da wọn pada siluu koowa wọn bayii.
Ọkan pataki lara awọn ọga agba ẹka ileeṣẹ to n ri sọrọ igbe aye idẹrun laarin ilu, ti o wa niluu Abuja, Alhaji Sani Amar-Rabe, lo sọrọ ọhun di mimọ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, lẹyin ti wọn da gbogbo awọn onibaara ọhun pada siluu koowa wọn.
Alhaji Sani Amar-Rabe ni Minisita fun ilu Abuja, Dọkita Ramatu Aliyu, lo paṣẹ pe ki awọn ko gbogbo awọn onibaara ti wọn kan n rin kaakiri aarin ilu Abuja kuro, ki wọn si da wọn pada siluuti kaluku wọn ba ti wa loju-ẹsẹ.
O ni ki i ṣe awọn onibaara nikan lawọn da pada o, awọn tun da gbogbo awọn ọmọde ti wọn ko ni ibi kan pato ti wọn n gbe, to jẹ pe ṣe ni wọn kan n rin kaakiri aarin ilu naa ni pada siluu ti wọn ti wa bayii.
O ni ‘A ti da gbogbo awọn onibaara ti wọn n tọrọ owo lọwọ awọn araalu, pẹlu awọn ti wọn ko niṣẹ gidi lọwọ to jẹ pe ko sibi ti wọn ko le sun si bi alẹ ba lẹ pada siluu koowa wọn, a yẹ awọn kọọkan wo boya wọn ni arun tabi pe ara wọn ko da, a tun gbiyanju lati kọ awọn kọọkan niṣẹ ọwọ, awọn to ṣetan lati kọṣẹ ọwọ, a yọ wọn sọtọ, awọn ti ko ṣetan lati kọṣẹ, a tun yọ awọn naa sọtọ pẹlu. A ko fẹ awọn ẹni to jẹ pe wọn ko fẹ iṣẹ ṣe rara laarin ilu mọ
‘‘Ọpọ lara awọn ta a da pada wa lati ipinlẹ Kano, Zamfara, Sokoto pẹlu Kebbi lọhun-un, iwọnba ni awọn onibaara to jẹ pe ilẹ Ibo lọhun-un ni wọn ti wa, awọn ta a ri lati ilẹ Ibo jẹ ọmọ ipinlẹ Abia, Imo pẹlu Delta.
Alhaji Sani Amar-Rabe ni loju-ẹsẹ lawọn ti pe awọn gomina awọn ipinle tawọn onibaara naa ti wa pe ki wọn ṣetọju awọn eeyan wọn daadaa, paapaa ju lọ gbogbo awọn tawọn da pada naa.
O ni lara idi pataki tawọn onibaara ọhun fi n da wa siluu Abuja ni pe, wọn gbagbọ pe eto aabo to peye wa fawọn niluu naa.
Bakan naa ni Alhaji Sani Amar-Rabe rọ awọn araalu Abuja pe ki wọn yee fun awọn onibaara gbogbo lowo, nitori pe bi wọn ṣe n rowo gba lọwọ awọn araalu lo n fun wọn ni iwuri lati maa sa wa siluu naa bayii.