Ẹ yi ẹjọ ti Peter Obi ati ẹgbẹ Labour pe ta ko Tinubu danu-INEC

Monisọla Saka

Lori awuyewuye to ṣu yọ lẹyin idibo sipo aarẹ, to waye ninu oṣu Keji, ọdun yii, ajọ eleto idibo ilẹ wa (INEC), ti fara han niwaju ile-ẹjọ Tiribuna, lati sọ idi to fi jẹ pe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ati igbakeji ẹ, Kashim Shettima, ni wọn kede bii ẹni to jawe olubori ninu ibo ọhun.

Bakan naa ni ajọ yii tun rawọ ẹbẹ si kootu to n gbọ ẹjọ to ba ṣu yọ latara eto idibo, eyi to fikalẹ sinu ile-ẹjọ Kotẹmilọrun ilẹ wa (Court of Appeal), niluu Abuja, lati da ẹjọ ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati oludije funpo aarẹ lẹgbẹ naa, Peter Obi, pe nu, nitori wọn o le ri awọn nnkan ti wọn beere fun lọwọ ile-ẹjọ gba.

Ajọ eleto idibo ni awọn oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Shettima, kunju oṣuwọn, bẹẹ ni wọn ṣe gbogbo nnkan to yẹ ni ṣiṣe, nitori bẹẹ lawọn ṣe kede wọn bii ẹni to wọle, tawọn si tun fun wọn niwee-ẹri.

INEC ni olujẹjọ akọkọ, ninu iwe ẹsun ti Peter Obi to duro bii olupẹjọ akọkọ pe, ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party funra ẹ si jẹ olupẹjọ keji. Ajọ INEC, Tinubu, Shettima ati ẹgbẹ oṣelu APC ni wọn pe lẹjọ ninu iwe ẹsun naa.

Ninu esi wọn si ẹsun yii, eyi ti wọn fi ranṣẹ pada sile-ẹjọ to n gbọ ẹsun idibo lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni agbẹjọro fun ajọ INEC, Abubakar Mahmoud, ti rawọ ẹbẹ sile kootu naa lati yi ẹjọ ti wọn pe yii danu, tabi ki wọn wọgi le e, nitori ko kun oju oṣuwọn, ibinu ati ikanra ti ko lori ti ko si nidii, to jẹ ọtẹ atawọn ọrọ ti ko ṣee gbọ seti lo kun inu ẹjọ ti wọn pe ọhun.

Ninu ẹjọ tawọn ẹgbẹ Labour ati Peter Obi pe yii ni wọn ti sọ pe ki wọn fagi le ibo to waye lọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, eyi to gbe Tinubu ati Shettima wọle.

Peter Obi ati aṣaaju ninu awọn agbẹjọro wọn, Livy Ozoukwu, tun sọ pe ọpọlọpọ awọn ibo to ba ofin mu lasiko idibo kọ lo gbe Tinubu wọle.

Wọn ni odidi ipinlẹ mọkanla ni magomago eto idibo ti waye, ati pe awọn le fi eyi han ninu awọn esi idibo ti ajọ INEC gbe jade.

Wọn tẹsiwaju pe ajọ INEC ni tiẹ ru ofin tawọn funra wọn ṣe, nigba ti wọn lọọ kede esi idibo pẹlu bo ṣe jẹ pe ki i ṣe gbogbo ibo ti wọn di lawọn ibudo idibo ni wọn ti gbe sori ayelujara fawọn eeyan lati ri lasiko ti wọn kede iye ibo to wọle ati ẹni to gbegba oroke.

Ninu esi tiwọn, ẹgbẹ oṣelu APC ni ki ile-ẹjọ yi ẹjọ ti Peter Obi pe danu bii omi iṣanwọ, nitori ẹjọ naa ko lẹsẹ nilẹ, ati pe ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ Labour Party ni nnkan bii ọgbọnjọ si asiko ti wọn ṣeto idibo abẹle ẹgbẹ wọn.

Wọn ni, “Ọmọ ẹgbẹ oṣelu People’s Democratic Party (PDP), ni Obi titi di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2022, wọn si ṣayẹwo fun un gẹgẹ bii oludije dupo aarẹ ninu ẹgbẹ PDP ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2022 bakan naa.

Olupẹjọ akọkọ kopa ninu eto naa, wọn si kede ẹ bii ẹni ti yoo dupo aarẹ lasiko to wa ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.

“Lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2022 yẹn naa, ni Obi kọwe fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lati darapọ mọ olupẹjọ keji, ti i ṣe ẹgbẹ oṣelu Labour Party, lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2022.

Ọgbọnjọ, oṣu Karun-un, ọdun to lọ yii, ni ẹgbẹ oṣelu Labour ṣeto idibo abẹle wọn, leyii to gbe Peter Obi wọle gẹgẹ bii oludije sipo aarẹ wọn, eleyii si ta ko ofin eto idibo “.

Wọn ni iwe ẹsun ti wọn pe ta ko ẹgbẹ APC ati Tinubu yii ko lẹsẹ nilẹ to, niwọn igba to ti jẹ pe orukọ Peter Obi ko si lori iwe ti ẹgbẹ Labour Party gbe lọ siwaju ajọ INEC, lasiko to darapọ mọ ẹgbẹ naa.

Wọn tun ni Alaaji Atiku Abubakar lo ni ibo to pọ ju lẹyin Tinubu, ati pe olupẹjọ gan-an lo mu ipo kẹta ninu ibo naa, nitori idi eyi, ẹgbẹ APC rọ ile-ẹjọ to n gbọ ẹsun idibo yii lati sọ boya Peter Obi lo ni ibo to pọ ju, lai dara pọ mọ Atiku ninu ẹjọ ti wọn pe.

Ẹgbẹ APC waa rọ ile-ẹjọ lati da ẹjọ tawọn Obi ati ẹgbẹ oṣelu Labour pe nu nitori bi ko ṣe kun oju oṣuwọn.

Leave a Reply