Monisọla Saka
Pẹlu bi wọn ṣe n palẹmọ lati maa ra epo bẹtiroolu wọlu latilẹ okeere, ẹgbẹ alagbata epo rọbi ti sọrọ lori iye owo tuntun ti wọn yoo maa ta epo lawọn apa ibi kan lorilẹ-ede yii. Adari ajọ to n ta epo bẹtiroolu lorilẹ-ede yii, Independent Petroleum Marketers Association of Nigeria (IPMAN), Mike Osatuyi, ṣalaye pe latinu oṣu Keje, ọdun yii lọ, o ṣee ṣe ki wọn maa ta jala epo kan ni ẹẹdẹgbẹrin (700), lawọn ipinlẹ apa Ariwa orilẹ-ede yii.
L’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni Osatuyi sọrọ yii di mimọ lasiko ifọrọwerọ kan to ṣe.
O ni ni kete tawọn alagbata epo yii ba ti bẹrẹ si i raja wọle ninu oṣu Keje, awọn eeyan apa Ariwa yoo maa ra epo jala kan ni bii ẹẹdẹgbẹrin Naira tabi ju bẹẹ lọ, nigba to ni kawọn ti wọn n gbe lawọn ipinlẹ mi-in yatọ si Eko maa gbaradi lati maa ra a ni bii ẹgbẹta Naira ati Naira mẹwaa (610), nitori ẹgbẹta Naira (600), lawọn eeyan ipinlẹ Eko yoo maa ra tiwọn.
O ni, “Gẹgẹ bi nnkan ti mo n wo, yoo maa to ẹgbẹta Naira tabi ju bẹẹ lọ lati ra jala epo kan, eleyii tun da lori iye ti wọn ba n ṣẹ owo nigba naa, to fi mọ iye ti wọn ba n ta epo rọbi lọwọ bayii lọja agbaye, ati iye ti yoo ba wọlu. Awọn to wa l’Ekoo yoo maa san bii ẹgbẹta Naira, tawọn to n gbe nipinlẹ ti ki i ṣe Eko yoo le ọwọ diẹ si nigba tawọn ti apa oke ọya yoo maa to ẹẹdẹgbẹrin Naira tabi ju bẹẹ lọ”.
O tẹsiwaju pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa ṣi wa lẹnu eto iwe aṣẹ ti wọn n fawọn ti wọn fẹ maa ṣowo epo rọbi rira latilẹ okeere.
Bakan naa lo tun sọ pe Olufẹmi Adewọle, ti i ṣe akọwe agba awọn ajọ to n ṣe agbata epo rọbi fidi ẹ mulẹ pe wọn ṣi n fawọn eeyan niwee aṣẹ lati maa ra epo wọle.
O ni wọn n ṣeto lọ lai dawọ duro lori epo tuntun ti wọn fẹẹ gbe wọle ninu oṣu Keje, ati pe iru ọja ti wọn ba ra ati inawo to ba gori ẹ ki wọn to gbe e dele ni yoo sọ iye ti wọn yoo maa ta a lagbegbe kọọkan lorilẹ-ede yii.