Eedi ree o! Ileeṣẹ ologun yin ado oloro pa eeyan marundinlaaadọrun-un wọn lawọn ro pe Boko Haram ni wọn

Faith Adebọla

Owe Yoruba to ni ogun ni i ṣi’ni i mu, epe ki i ṣi’ni ja, ti ṣẹ mọ awọn olugbe ipinlẹ Kaduna kan lara pẹlu bi awọn ọmọ-ogun ilẹ wa ṣe lọọ rọjo ado iku abugbamu sori awọn eeyan ti wọn n ṣe ajọyọ lọwọ labule wọn, ti wọn si pa eeyan to ju marundinlaaadọrun-un (85) lọ lẹyẹ-o-sọka, wọn lawọn ṣi wọn mu ni, awọn ro pe awọn agbebọn ati afẹmiṣofo ni wọn ni.

Iṣẹlẹ ibanujẹ to da bii eedi yii waye ni nnkan bii aago mẹsan-an aṣaalẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹta, oṣu Kejila, ọdun 2023, niluu Tundun Buru, nijọba ibilẹ Igabi, nipinlẹ ọhun.

Ọkan ninu awọn olugbe agbegbe ọhun tiṣẹlẹ yii ṣoju rẹ, amọ ti ko fẹ ki wọn darukọ oun sọ pe:

“Ọdun Maulud, iyẹn ayẹyẹ ti wọn fi n sami ọjọọbi Anọbi Muhammad la n ṣe lọwọ ni Sannde naa, ojiji la kan ri baaluu agbera-paa awọn ọmọ-ogun to n fo kọja loju ọrun, latinu ẹ ni wọn ti ju bọmbu silẹ saarin wa, eeyan ọgbọn lo gbẹmi-in mi lẹsẹkẹsẹ, ọpọ si fara gbọgbẹ yanna-yanna.”

Nigba ti wọn n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, ajọ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, tijọba apapọ, National Emergency Management Agency, NEMA, sọ loju opo fesibuuku rẹ lalẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keji iṣẹlẹ yii pe iye oku eeyan to ba ajalu buruku yin rin, tawọn ti ṣa jọ, ti wọn si ti sin awọn kan ninu wọn, ti di marundinlaaadọrun-un (85) bayii.

Yatọ si tawọn to ku iku gbigbona yii, atẹjade ajọ NEMA tun fi kun un pe, “awọn oṣiṣẹ ẹka ileeṣẹ wa, ti ẹkun Ariwa/Iwọ-Oorun ti ṣabẹwo si ọsibitu Barau Dikko, nibi ti awọn to fara gbọgbẹ loniran-iran wa, eeyan mẹrindinlaaadọrin (66) lawọn dokita ṣi n tọju lọwọ nibẹ.”

Iṣẹlẹ yii lo ti fẹẹ da ifẹhonuhan ati idarudapọ silẹ lagbegbe ọhun, pẹlu bawọn olori ẹsin atawọn alẹnulọrọ nipinlẹ Kaduna ṣe bẹnu atẹ lu ileeṣẹ ologun ilẹ wa fun iru aṣiṣe to gbomi loju araalu bii eyi. Ajọ NEMA ni iporuuru ọkan, ibinu, ẹhonu ati ikanra gidi lo n ṣẹlẹ lọwọ ni gbogbo agbegbe tọrọ yii kan, idi si niyi tawọn ko ṣe le ṣabẹwo ibanikẹdun si awọn mọlẹbi ti wọn fara gba ninu ajalu ọhun.

Amọ, bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ologun oju ofurufu ilẹ wa, iyẹn Nigeria Air Force, mọ lori ajalu yii, wọn lawọn ko mọ nnkan kan nipa rẹ rara ni tawọn. Ileeṣẹ ologun ilẹ wa, eyi to jẹ agbarijọpọ awọn ọmoogun oju ofurufu, awọn jagunjagun ori-omi atawọn ti ori ilẹ, Nigeria Army, ti sọ pe ọwọ awọn ni aṣiṣe naa ti waye, ti wọn si tọrọ aforiji lọwọ gbogbo ẹni tọrọ ọhun kan.

Ninu atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto aabo ati ọrọ abẹle nipinlẹ Kaduna, Ọgbẹni Samuel Aruwan, fi lede lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrin, oṣu Kejila yii, o ni awọn ti ṣepade, ipade ṣi n lọ lọwọ pẹlu awọn aṣaaju ẹsin Musulumi, awọn alaṣẹ ilu gbogbo, awọn ori-ade atawọn alẹnulọrọ lati foju ṣunnukun wo iṣẹlẹ ibanujẹ yii, ki wọn si feegun otolo to o.

Nibẹ lo ti sọ pe ọga agba kan nileeṣẹ ologun, iyẹn General Officer Commanding 1 Division of Nigeria Army, Mejọ Jẹnẹra Valentine Okoro, ti ṣalaye bi iṣẹlẹ aṣiyin bọmbu naa ṣe jẹ.

Wọn l’Okoro ṣalaye pe bawọn ọmoogun ilẹ wa ṣe maa n ṣe patiroolu oju ofurufu wọn loorekoore naa ni wọn ṣe e, to si jẹ pe nibikibi ti wọn ba ti kẹẹfin pe awọn afẹmiṣofo, awọn agbebọn tabi awọn ikọ mujẹmujẹ Boko Haram n kora jọ ninu igbo nibikibi, ẹni ba yara l’ogun i gbe lawọn n fi ọrọ wọn ṣe, lẹyẹ-o-sọka lawọn maa n fi akara iku ṣọwọ si wọn, lojuna ati kapa eto aabo to mẹhẹ ati itajẹsilẹ to n waye lapa Oke-Ọya. Amọ o ṣe ni laaanu pe lọtẹ yii, araalu lawọn ṣi mu, aṣiṣe o si lọgaa.

Wọn tọrọ aforiji, wọn si rawọ ẹbẹ sawọn mọlẹbi pe ki wọn jeburẹ lori ajalu buruku yii.

Titi dasiko ta a fi n ko iroyin yii jọ ni lọgbọ-lọgbọ ati aifararọ ṣi n ṣẹlẹ nipinlẹ Kaduna, paapaa lagbegbe ijọba ibilẹ Igabi, ti ado aloro ọhun ti ṣọṣẹ rẹpẹtẹ.

Leave a Reply