Eedi ree o! Mustapha gun ọrẹ ẹ lọbẹ pa l’Ọrẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Kootu Majisireeti to wa lagbegbe Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, ti ni ki ọkunrin ẹni ọdun mejilelọgbọn kan, Atahiru Mustapha, ṣi lọọ maa ṣere ninu atimọle awọn agbofinro lori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.

ALAROYE gbọ pe ninu ọja Sabo, to wa niluu Ọrẹ, n’ijọba ibilẹ Odigbo, niṣẹlẹ yii ti waye  ni nnkan bii aago meje aabọ alẹ ọjọ kẹta, oṣu Kẹta, ọdun yii.

Mustapha to jẹ oniṣowo ni wọn fẹsun kan pe o fi ibinu gun ọrẹ rẹ, Usairu Umaru, lọbẹ nikun nitori ede aiyede kekere to waye laarin awọn mejeeji lọjọ iṣẹlẹ naa.

Agbefọba, Simon Wada, ni loootọ lawọn alaaanu kan sare gbe ọmọ naa digbadigba lọ sile-iwosan lẹyin ti ọrẹ rẹ gun un lọbẹ. Ọsibitu ọhun lo ni awọn dokita ti fidi rẹ mulẹ pe ọkunrin ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn naa ti ku latari oju ọgbẹ ọbẹ to wa lara rẹ.

Wada ni ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan olujẹjọ ọhun ta ko abala okoo le lọọọdunrun din ẹyọ kan (319), to si tun ni ijiya to lagbara labẹ abala okoo le lọọọdunrun dín mẹrin (316) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Agbefọba waa bẹ adajọ pe ko fi olujẹjọ naa pamọ sinu ọgba ẹwọn titi digba ti kootu yoo fi rí imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Agbẹjọro afurasi ọdaran ọhun, Amofin Jolówó,  ta ko aba yii, o ni o niye gbedeke ọjọ ti ofin la silẹ fun olujẹjọ lati fesi si iru ẹbẹ ti agbefọba fi siwaju adajọ.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Kọlawọle A. Aro, ni ki wọn ṣi da afuarsi apaayan naa pada si atimọle awọn ọlọpaa titi di ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024.

Leave a Reply