Eedi ree o! Nitori ọrọ ti ko to nnkan, Oluranti yin iyawo ẹ lọrun pa

Gbenga Amos, Ogun

Ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Eleweẹran, ti i ṣe olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, l’Abẹokuta, ni ọkunrin ẹni ọdun mọkanlelaaadọta kan, Oluranti Badejọ wa bayii, latari bo ṣe lu iyawo ẹ, Felicia Badejọ pa, lori ọrọ ti ko to nnkan ni Mowe.

Ojule keje, Opopona Madam Felicia, laduugbo Orimẹrunmu, niluu Mowe, niṣẹlẹ yii ti waye lọjọ kejila, oṣu Kẹwaa, ọdun yii.

SP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, ni aburo oloogbe naa lo sare janna-janna lọọ fẹjọ sun lẹka ileeṣẹ ọlọpaa to wa ni Mowe, o ni ẹgbọn oloogbe naa to n gbe lọdọ wọn lo pe oun lori aago pe koun tete lọọ pe ọlọpaa o, tori Badejọ ti pa aunti oun.

DPO teṣan naa, SP Fọlake Afẹnifọrọ, yan awọn ọlọpaa tẹle ọmọbinrin yii lati lọọ wo ohun to ṣẹlẹ, wọn ba oku Fọlaṣade nilẹẹlẹ, wọn si faṣẹ ọba mu afurasi ọdaran to pa a. Lẹyin eyi ni wọn gbe oku oloogbe naa lọ si mọṣuari ileewosan Jẹnẹra Ṣagamu, fun ayẹwo, lati mọ’ru iku to pa a gan-an.

Awọn ọlọpaa ni iwadii ti wọn ṣe fihan pe niṣe lọkunrin naa fibinu yin iyawo ẹ lọrun pa, nigba ti ariyanjiyan wẹrẹ kan dija laarin wọn.

Wọn ni nigba toju ẹ walẹ, to ri i pe ẹmi eeyan ti tọwọ oun bọ ni jẹbẹtẹ gbọmọ le e lọwọ, eyi lo mu ko da ọgbọnkọgbọn kan, wọn lo tanna si aayẹni wọn, o si dọgbọn fi i jo oloogbe naa lara kaakiri, o tun tu waya ina ẹlẹntiriiki ile ẹ silẹ, ko le da bii pe ina mọnamọna lo gbe obinrin naa to fi ku.

Ṣugbọn gbogbo aṣiri irọ yii ko bo rara, tori gbogbo ohun to ṣẹlẹ pata to lo ṣoju Jumọkẹ, ọmọọdun mẹjọ, to jẹ ọmọ wọn. Ọmọ ọhun lo ṣalaye pe baba oun lo yin iya oun lọrun to fi ku. O ni niṣe ni baba oun n wo oloogbe naa niran bo ṣe n japoro iku, ko si fọwọ kan an titi to fi gbẹmi-in mi.

Ọgbẹni Lekan Yusuf, to jẹ ọkan lara awọn aburo oloogbe naa sọ fakọroyin Punch pe aladuugbo wọn lo pe oun sori aago lati fi iṣẹlẹ aburu naa to oun leti toun fi n sare bọ.

O ni gbara toun debẹ laaarọ ọjọ naa, oun ri apa aayẹni lara aunti oun, ẹjẹ si n jade nimu ati eti ẹ.

“Gbogbo igba lawọn mejeeji maa n ja nigba ti mo fi n gbe lọdọ wọn l’Ajegunlẹ, ki wọn too ko wa si Mowe, niṣe l’Oluranti maa n lu ẹgbọn mi bii ẹni luṣọ ofi to ba ti tibi iṣẹ de, ọrọ ti ko to nnkan lo maa n binu rangbandan le lori, lọjọ kan, anti mi n sun lọwọ ni nigba to bẹrẹ si i lu u tibinu tibinu,” gẹgẹ bo ṣe wi.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Bankọle, ti paṣẹ pe kawọn ọtẹlẹmuyẹ lẹka ti wọn ti n boju to iwa ọdaran abẹle ṣi maa ba iṣe iwadii wọn niṣo na, o lafurasi naa maa kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ laipẹ.

Leave a Reply