Eedi ree o! Tọpẹ fun iya rẹ lọrun pa n’Ikakumọ Akoko, o lo pe oun lọmọ ale

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Boya ẹfun ni ka pe ọrọ ọhun ni tabi eedi, ko sẹni to ti i le sọ  pẹlu bi ọmọkunrin kan ti wọn porukọ rẹ ni Tọpẹ Momoh ṣe fun iya rẹ, Abilekọ Stella Momoh, lọrun pa mọ inu yara ile wọn niluu Ikakumọ Akoko, n’ijọba ibilẹ Ariwa Ila-Oorun Akoko, loru ọjọ kẹfa, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022 ta a wa yii.

Ohun ta a gbọ nipa iṣẹlẹ ọhun ni pe ni kete ti iya ẹni ọdun mejilelaaadọta naa ti dagbere faye lawọn ẹbi rẹ ti ko ara wọn jọ, ti wọn si ṣeto isinku rẹ lai fura rara pe iku to ku ki i ṣe atọrun wa.

Lẹyin ọsẹ meji ti wọn ti sinku rẹ ni ọmọ rẹ, iyẹn Tọpẹ, ṣẹṣẹ sare lọọ ba awọn eeyan kan ti wọn jẹ mọlẹbi rẹ, to si jẹwọ fun wọn pe iku iya naa ko sẹyin oun.

Gẹgẹ bi alaye ti afurasi ọmọ ọdun mejidinlogun ọhun fẹnu ara rẹ ṣe nigba to n jẹwọ fawọn ọlọpaa to fọrọ wa a lẹnu wo, o ni oun loun fun iya oun lọrun pa latari bo ṣe n pe oun l’ọmọ ale.

O ni oun fi ibinu ran obinrin naa sọrun ọsan gangan pẹlu bo ṣe deedee ji oun dide lati oju oorun loru ọjọ iṣẹlẹ naa, to si n ṣẹ epe le oun lori kikankikan, to tun ni ọmọ ale loun.

Afurasi naa nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti wọ lọ sile-ẹjọ Majisireeti kin-in-ni l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, nibi ti wọn ti fẹsun ipaniyan kan an.

Ẹsun yii ni Agbefọba, Nelson Akintimẹhin, ni o ta ko abala okoolelọọọdunrun din ẹyọ kan (319) ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Akintimẹhin bẹbẹ pe ki wọn fi olujẹjọ naa pamọ sinu ọgba ẹwọn Olokuta titi tile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Ninu ọrọ diẹ to sọ nile-ẹjọ, Tọpẹ ni ki adajọ siju aanu wo oun niwọn igba to jẹ pe funra oun loun lọọ jẹwọ nipa iṣẹlẹ naa fawọn ẹbi oun latari ẹri ọkan ti ko jẹ ki oun sinmi lẹyin ti oun pa iya oun tan.

Onidaajọ Musa Al-Yunus paṣẹ pe ki afurasi ọhun ṣi lọọ maa gbatẹgun ni ọgba ẹwọn Olokuta, titi di igba ti igbẹjọ yoo tun maa tẹsiwaju logunjọ, oṣu ta a wa yii.

Leave a Reply