Eefi ina eedu ti tọkọ-taya da sinu ile nitori otutu ṣeku pa wọn

Monisọla Saka

Adura nla to yẹ ki eeyan maa ṣe amin si ti wọn ba ti n  gba a ni pe ki Ọlọrun ma jẹ ka toju oorun de oju iku. Ọkọ atiyawo kan, Sulaiman ati Maimuna, ti ku lasiko ti wọn n sun lọwọ nitori eefin ina ti wọn da sinu yara wọn to wọ wọn nimu.   

Gogoogo ni abule Kwa, to wa nijọba ibilẹ Dawakin Tofa, nipinlẹ Kano, nibi ti tọkọ-tiyawo naa, Sulaiman Idris, ẹni ọdun mejidinlọgbọn (28), atiyawo ẹ, Maimuna Halliru, ẹni ogun ọdun (20) n gbe kan. Eyi ko sẹyin bi awọn mejeeji ṣe dero ọrun kilẹ too mọ latari ina eedu ti wọn sọ pe wọn da sinu yara wọn.

ALAROYE gbọ pe nitori apọju otutu to n mu lẹnu ọjọ mẹta yii lo mu ki tọkọ-taya naa da ina eedu, ti wọn si gbe e sinu yara ti wọn n sun ki ooru le baa mu wọn. Ṣugbọn o jọ pe wọn sun gbagbe titi ti eefin ina ti wọn da naa fi gba gbogbo inu yara ti wọn wa, ti ko si ribi kankan gba jade sita. Eefin yii la gbọ pe o ko si wọn lọkan, to si ṣeku pa wọn lasiko ti wọn n sun lọwọ lọjọ kẹta, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023 yii, ni nnkan bi aago mẹsan-an alẹ. N lawọn tọkọ-tiyawo naa ba toju oorun de oju iku.

Nigba tawọn alajọgbele wọn yoo si fi ṣakiyesi wọn, oku awọn mejeeji ni wọn ba lori ibusun wọn.

Oṣu mẹwaa sẹyin ni wọn ni Sulaiman, gbe ololufẹ ẹ niyawo.

 Iya Sule, Mallama Binta Muhammad, ṣalaye pẹlu ibanujẹ ati omije loju pe, ohun ibẹru niroyin iku ọmọ oun atiyawo ẹ jẹ foun nigba toun gba ipe pe wọn ti jade laye.

O ni, “N o tiẹ le sọ bọrọ naa ṣe ri lara mi nigba ti wọn tufọ fun mi, majele ni mo tiẹ kọkọ ro pe wọn fun awọn ọmọ naa jẹ ko too di pe wọn pada ṣalaye fun mi pe ina eedu ti wọn da sinu ile lati din otutu ku lo ko si wọn lọkan, to pa wọn mọjumọ.

‘’Emi atawọn tọkọtaya naa ko gbe pọ ninu ilu kan naa, ṣugbọn a ṣi sọrọ ni bii ọjọ mẹta sẹyin. Afi bii ẹni pe wọn ti mọ nnkan to fẹẹ ṣẹlẹ ni, nigba ta a sọrọ gbẹyin ni wọn ṣaa n tẹnu mọ ọn fun mi pe ki n bawọn ki awọn aburo awọn. Aṣe ọrọ asọgbẹyin emi pẹlu wọn niyẹn. Sule to doloogbe yii ni akọbi mi, aburo mẹsan-an lo si ni lẹyin”.

Pẹlu omije loju ati ẹdun ọkan ni Abilekọ Maryam Muhammed, iya iyawo fi sọrọ. O loun o ti i gbagbọ pe iru iṣẹlẹ bayii waye, pe bawo leeyan ṣe n ṣadeede ku bẹẹ.

Ninu ọrọ tiẹ, ọrẹ Sule to tun jẹ alabaagbe ẹ, Hussaini Zakiru, juwe oloogbe bii ẹni to lọyaya, to lẹran ifẹ lara, to si kooyan mọran. O loun ṣi ri oloogbe lọjọ tiṣẹlẹ naa maa waye ki kaluku too wọle sun.

Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kano, SP Abdullahi Haruna, sọ pe, iya to bi iya Sulaiman lo ṣakiyesi pe oun ko ri iwọle ati ijade tọkọtiyawo naa ninu ile wọn, nitori bẹẹ ni wọn ṣe fipa jalẹkun lẹyin ti wọn kanlẹkun titi tẹnikẹni ko da wọn lohun lati inu ile. Ibanujẹ lo jẹ fun wọn nigba ti wọn ri awọn mejeeji ti wọn ko le mira mọ lori ibusun ti wọn wa.

Haruna ni lojuẹsẹ ni wọn sare gbe tọkọtaya naa lọ sileewosan Murtala Muhammed Specialist Hospital, ni Kano, ibẹ lawọn dokita si ti fidi rẹ mulẹ pe awọn mejeeji ti ku.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kano ti waa rọ awọn eeyan ipinlẹ naa lati ṣọra fiun lilo ina igi ati ti ẹlẹntiriiki, ki wọn si ṣe pẹlẹpẹlẹ, paapaa ju lọ lasiko ọgbẹlẹ ati ọyẹ ta a wa yii, to jẹ pe iṣẹlẹ ijamba ina maa n wọpọ gidi gan-an.

Leave a Reply