Adewale Adeoye
Oku baale ile kan, Oloogbe Nwachuku, toun ati iyawo rẹ n gbe lagbegbe Shogoye, niluu Owode-Ẹgba, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, ni wọn ba ninu ile l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, nigba tiyawo rẹ, Abilekọ Oyin Falọdun, wa lẹsẹ-kan-aye ẹsẹ-kan-ọrun nileewosn ijọba kan to wa lagbegbe naa lẹyin ti oloogbe ati iyawo rẹ fa eefin jẹnẹretọ simu.
ALAROYE gbọ pe ṣe lawọn tọkọ-taya naa gbe jẹnẹretọ ti wọn tan lọjọ naa sinu palọ wọn, nigba tawọn wa ninu iyara. Wọn gbagbe sun lọ, ni eefin ẹrọ amunawa yii ba ko si wọn nimu, eyi to ṣokunfa iku ojiji fun ọkọ.
Ọgbẹni Ọlaṣubomi ti i ṣe ọkan lara awọn araale ibi ti wọn n gbe to fẹẹ waa da ajọ sọwọ iyawo lo ṣakiyesi pe nnkan aburu ti ṣẹlẹ, onitọhun lo figbe bọnu, tawọn araadugbo si waa wo ohun to ṣẹlẹ si wọn lọjọ yii.
Alaga ẹgbẹ lanlọọdu aduugbo naa, Ọgbẹni Showunmi Sunday, lo lọọ fiṣẹlẹ ohun to awọn agbofinro Owode-Ẹgba leti.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, sọ pe awọn ọlọpaa agbegbe naa ti lọ sibi iṣẹlẹ ọhun, wọn ba oku oloogbe naa ninu yara, bẹẹ ni won sare gbe iyawo rẹ lọ sileewosan Ore-Ọfẹ, to wa lagbegbe naa fun itọju to peye. Ibẹ naa lo wa to ti gbiyanju lati sọ biṣẹlẹ ọhun ṣe waye fawọn ọlọpaa. O ni ni nnkan bii aago mẹwaa aṣaalẹ ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, loun beere lọwọ ọkọ oun boya koun lọọ pa jẹnẹretọ naa, ṣugbọn to ni k’oun oo fi i silẹ, ṣugbọn to jẹ pe ṣe lawọn gbagbe sun lọ lọjọ yii, tawọn mejeeji si pada fa eefin jẹnẹretọ naa simu, eyi to ṣokunfa iku ọkọ oun lojiji.