Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Titi di ba a ṣe n kọ iroyin yii lọrọ iku awọn gende mẹta kan si n ṣe awọn ẹbi wọn ni kayefi. Awọn oloogbe ọhun, Samuel Louis, ẹni ọdun marundinlaaadọta, Akinmusire Monday, ẹni ọdun marundinlogoji ati Ododolẹwa Adebọwale ni wọn ba oku wọn ninu igbo kan ni Ọmọtọṣọ, lagbegbe Akinfọsile, nijọba ibilẹ Okitipupa, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja.
ALAROYE gbọ lati ẹnu ọkan lara awọn ẹbi awọn to ku ọhun pe iṣẹ agbasẹ ni Louis n ṣe, nigba ti Monday n ṣiṣẹ awọn to n fi ẹrọ lagi kaakiri inu oko
Adebọwale to kere ju ninu wọn ni wọn lo ṣi n ṣe idanwo Waẹẹki lọwọ. Aajo aje lo ni koun sare ṣe lọjọ naa lai mọ pe iṣẹ ti yoo la ẹmi rẹ lọ lo fẹẹ gun le.
Louis ni wọn lo bẹ awọn mejeeji lọwẹ lọjọ ta a n sọrọ rẹ yii lati lọọ ba a ṣiṣẹ igi gige ninu igbo ijọba to wa lagbegbe Ọmọtọṣọ, ṣugbọn tawọn eeyan wọn ko ri awọn mẹtẹẹta ki wọn pada sile ti wọn ti kuro ni Akinfọsile.
Aburo Monday, Emmanuel Akinmusire, ni nigba tawọn reti awọn eeyan ọhun titi tawọn ko ri i ki wọn pada wale loun atawọn eeyan kan lọ sinu igbo ibi ti wọn ti lọọ ṣiṣẹ naa boya awọn ṣi le ri wọn.
O ni gbogbo akitiyan awọn lati ṣawari wọn lọjọ naa lo ja si pabo, ọkada ti wọn gun wọ inu igbo nikan lawọn ba nibi ti wọn gbe e ju si.
Lẹyin eyi lo ni awọn sẹsẹ pada saarin ilu lati waa fi iṣẹlẹ yii to Olufara tilu Akinfọsile, Ọba Ọlamide Ayọdele leti.
Kabiyesi lo lọọ fọrọ yii to awọn ọlọpaa, figilante atawọn Amọtẹkun to wa lagbegbe naa leti, ti gbogbo wọn si tun jọ jumọ pada sinu igbo naa lati wa awọn gende mẹtẹẹta ọhun lọnakọna.
O na awọn ẹsọ alaabo ọhun ni ọpọlọpọ wahala ki wọn too ṣalabaapade awọn eeyan naa ninu koto nla kan ti wọn ku si. Ọmọkunrin yii ni lẹyin ayẹwo lawọn ṣakiyesi pe o ṣee ṣe ko jẹ atẹgun kẹmika to n jade lati ẹnu ẹrọ nla tawọn ara China kan fi n ṣiṣẹ lagbegbe ọhun lo ṣokunfa iku wọn. Oku awọn awọn mẹtẹẹta ṣi wa ni mọsuari ileewosan aladaani kan niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni eefin kẹmika to n jade lati ẹnu ẹrọ ti wọn fi n ṣiṣẹ nileeṣẹ nla kan to wa nitosi inu igbo ti wọn ti n ge igi lo ṣokunfa ijamba ọhun.
O ni awọn ẹbi awọn to ku atawọn to ni ileesẹ naa ti n jiroro lori ọna ti wọn fẹẹ fi yanju iṣẹlẹ yii nitunbi inubi.