Faith Adebọla
Pẹlu ibinu lawọn ero to wọ reluwee ijọba lati Kaduna si Abuja fi n sọko ọrọ sijọba apapọ lowurọ ọjọ Aje, Mọnde yii, nigba ti reluwee naa joye abiku soloogun di eke, ẹẹmẹta ọtọọtọ ni reluwee naa daku, bi wọn ṣe n tun un ṣe lo n taku.
Lati ibudokọ reluwee to wa ni Rigassa, nipinlẹ Kaduna, ni ọkọ naa ti gbera ni aago meje owurọ ọjọ Aje, Mọnde, ọpọ awọn to si wọ ọ ni wọn fẹẹ lọọ wọṣẹ l’Abuja, pẹlu ireti pe irinajo naa ko ni i ju bii wakati kan lọ.
Ba a ṣe gbọ, wọn ni ko ju bii iṣẹju mẹẹẹdogun tọkọ naa bẹrẹ irinajo rẹ lo bẹrẹ si i ṣe tikọ tikọ loju ọna, irin rẹ ko ja geere mọ, ẹnjinni ọkọ naa ko si ṣiṣẹ daadaa. Wọn ni inu igbo to wa lagbegbe Dutse, nijọba ibilẹ Chikum, nipinlẹ Kaduna, lo taku si.
Kia lawọn ẹnjinnia to n ba ọkọ naa ṣiṣẹ ti bẹrẹ si i yẹ agbari rẹ wo, wọn kọkọ tun un ṣe, wọn ṣina fun un, wọn si sọ pe kawọn ero to ti bọ silẹ wọle pada, ṣugbọn bo ṣe rin siwaju diẹ lo tun taku.
Bẹẹ lo ṣe lẹẹkeji ati lẹẹkẹta, eyi lo bi awọn ero naa ninu, tori o ti mu ki ọpọlọpọ tase aago ti wọn fẹẹ dẹnu okoowo ati ọfiisi wọn.
Ọkan ninu awọn ero to wọ reluwee naa, Ọgbẹni Midat Joseph, to jẹ Igbakeji akọwe ẹgbẹ awọn oniroyin Naijiria royin pe iṣẹlẹ naa baayan ninu jẹ gidi, tori inu igbo ni reluwee yii n taku si, jinnijinni nla lo si da bo awọn ero tori eto aabo to mẹhẹ lasiko yii, niṣe ni kaluku n gbadura kawọn janduku agbebọn ma lọọ ka wọn mọ.
O ni iriri buruku ni, o si ya oun lẹnu pe ọkọ tuntun tijọba lawọn ṣẹṣẹ ra lo ti di daku daji yii.
Ọkunrin naa sọ pe “Aago mẹsan-an aarọ lo yẹ ki n wọṣẹ l’Abuja, ṣugbọn wọn o ri reluwee yii tunṣe titi di aago mẹwaa aabọ, ninu igbo kijikiji. Mi o gbadura ki iru nnkan yii tun ṣẹlẹ, ko daa rara.”
Ọkan ninu awọn ero mi-in sọ pe, laye oun, oun o tun ba wọn wọ reluwee naa mọ. O ni Ọlọrun lo yọ awọn ti awọn ko ko sọwọ awọn ajinigbe lasiko naa, niṣe ni wọn iba ru gbogbo awọn lọ sinu igbo.