Monisọla Saka
Iwọfun ni itẹlọrun, ko gba, ko dija, si lawọn eeyan maa n sọ. Ṣugbọn eyi ko ri bẹ fun baba afọju kan, Mudor George, ẹni ọdun mọkanlelaaadọrin (71), ti iyawo rẹ, Georgina, ẹni ọdun marundinlaaadọrin (65), halẹ mọ pe oun ko fẹ ẹ mọ, ni baba to nipenija oju yii ba yọ kẹlẹkẹlẹ lọ sibi ti obinrin naa sun si loru ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun yii, lo ba bẹ ẹ lori feu bii ẹran.
A gbọ pe ni nnkan bii ọdun mejidinlogun sẹyin ni tọkọ-tiyawo yii ti fẹ ara wọn, ti ohun gbogbo si n lọ deede fun wọn, ko too di pe aisan oju ki George mọlẹ, ti oju naa si ṣe bẹẹ fọ patapata. Wọn ni wahala itọju ọkunrin yii ati ẹjọ ojoojumọ to maa n ba iyawo rẹ ro lo su obinrin naa, eyi lo mu ko halẹ mọ ọn lọjọ yii pe oun maa kọ ọ silẹ. Ibinu eyi ni baale ile naa fi bẹ ori Georgina.
Ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ọkunrin ti ko gbadun oju rẹ ọhun, lẹyin to ṣeku pa iyawo ẹ lagbegbe Abepotia, ni Kwahu West Municipality, lorilẹ-ede Ghana.
Lọjọ kẹrinla, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni wọn ni George, bẹ ori iyawo ẹ, lasiko ti iya naa n sun lọwọ, lẹyin ọjọ bii meloo kan ti tọhun halẹ mọ ọn pe oun yoo kọ ọ silẹ.
ALAROYE gbọ pe ariyanjiyan kan lo bẹ silẹ laarin George atiyawo ẹ, to fi n bu obinrin ọhun pe alaimoore ni, o ni ko fẹmi imoore han si gbogbo nnkan toun ti ṣe fun un ko too di pe oju oun fọ, nitori gbogbo ohun ti oun ni loun fi ṣekẹ rẹ nigba ti oun gbogbo n lọ deede fun oun, ati pe ko yẹ ko maa halẹ mọ oun pe oun yoo kọ oun silẹ lẹyin ti oju oun fọ, ti nnkan ko si lọ deede mọ.
A gbọ pe ki i ṣe pe lati ibẹrẹ aye ọkunrin naa lo ti fọ loju, ni nnkan bii ọdun marun-un sẹyin ni wọn ni aisan kan kọ lu u, eyi to si gba oju lọwọ rẹ, to fi dẹni ti ko rina mọ.
Awọn alajọgbele ọkunrin naa sọ pe o da bii pe ọkunrin afọju yii ti ni in lọkan lati pa iyawo rẹ, nitori o ti kọkọ figba kan halẹ mọ ọn bẹẹ ri pe oun maa pa obinrin naa, ṣugbọn awọn ko ka ọrọ rẹ si nitori pe afọju ni. Ko sẹni to lero pe o le ṣeru nnkan bẹẹ pẹlu ipo to wa.
Nigba ti wọn gbe ọkunrin naa de kootu Majisreeti kan ti wọn n pe ni Nkawkaw, George sọ niwaju adajọ pe loootọ loun bẹ iyawo oun lori nitori pe o fẹẹ kọ oun silẹ. O waa ni ki Onidaajọ Isaac Agyei jọwọ, ṣiju aanu wo oun.
Ṣa, wọn ti gbe oku Georgina lọ sile igbokuu-pamọ-si Holy Family Hospital Morgue, fun ayẹwo iru iku to pa a, ti afurasi to da ẹmi obinrin naa legbodo si ti n naju lọwọ lakolo awọn ọlọpaa
Ọjọ karun-un, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni adajọ sun igbẹjọ mi-in lori ọrọ naa si.