Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọdọ awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ kan ti wọn n pe ni ‘Department Of State Security’ (DSS), ẹka tipinlẹ Ọsun, ni kọọṣi ẹgbẹ agbabọọlu kan niluu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, Ọgbẹni Adebisi, wa bayii, o n ran wọn lọwọ ninu iwadii wọn nipa ẹsun ti wọn fi kan an pe o fẹẹ fipa ba ọkan lara awn agbabọọlu rẹ to jẹ ọkunrin ṣe ‘kinni’ lọsẹ to kọja.
Ọkan lara olugbe agbegbe Isalẹ Ọṣun ti iṣẹlẹ ọhun ṣoju rẹ to gba lati ba awọn oniroyin sọrọ, ṣugbọn ti ko fẹẹ darukọ ara rẹ sita nitori idi pataki kan sọ pe Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii, lọwọ awọn DSS ti wọn fọrọ naa to leti tẹ Kọọṣi Adebisi, lasiko to fẹẹ fipa ba agbabọọlu rẹ sun, ti wọn si mu un lọ sahaamọ wọn.
ALAROYE gbọ pe inu ọgba ileewe girama kan ti wọn n pe ni ‘Fakunle Comprehensive High School’, to wa niluu Oṣogbo, nipinlẹ Ọṣun, ni Kọọṣi Adebisi ti pade agbabọọlu ọhun torukọ rẹ n jẹ Michael, lẹyin ti wọn pari eto igbaradi wọn tan lo ba pe agbabọọlu ọhun lọ sẹyin kilaasi kan, nibẹ lo ti n fọwọ kan an labẹ, o fọwọ tẹ nnkan ọmọkunrin rẹ wo daadaa lati mọ boya o le ṣe nnkan toun fẹ, ṣugbọn gbogbo bi Kọọṣi Adebisi ṣe n ṣe fọmọ naa ni Michael ko nifẹẹ si i rara, o gbiyanju lati sa mọ Kọọṣi naa lọwọ, ẹnu iwa palapala naa ti Kọọṣi ọhun wa ni ọkan lara awọn ọdẹ to n ṣọ inu ọgba ileewe naa ti kọja, loju-ẹsẹ ni awọn mejeeji ba tuka.
Nigba ti Michael dele awọn obi rẹ lo ṣalaye ohun ti oju rẹ ri lọwọ Kooṣi ni papa iṣere ‘Fakunle Comprehensive High School’, to wa niluu Oṣogbo.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘‘Mo mọ Kooṣi Adebisi daadaa, koda, mo mọ awọn agbabọọlu kọọkan to ti kọ ni bọọlu daadaa. Kọọṣi gidi ni, ṣugbọn ohun to ya mi lẹnu nipa ọrọ rẹ ni pe gbara ti mo pari eto igbaradi mi tan, lo ba pe mi lọ sinu kilaasi kan, ibẹ la wa to ti n yẹ nnkan ọmọkunrin mi wo, mi o nifẹẹ si eyi rara, ṣugbọn ko dawọ duro, afigba ti baba ọdẹ kan kọja lo too dawọ duro. Mo fọrọ naa to awọn ọrẹ mi kọọkan tawọn naa jẹ agbabọọlu leti, gbogbo wọn pata ni wọn bẹnu atẹ lu nnkan ti Kooṣi Adebisi ṣe pẹlu mi, wọn si gba mi lamọran pe, ki n di oju opo foonu to ti n ba mi sọrọ pa, ko ma baa lanfaani lati maa ba mi sọrọ lọjọ iwaju. Mo ṣe gẹgẹ bi wọn ṣe ti gba mi lamọran, ṣugbọn awọn agbalagba kọọkan ti mo tun fọrọ naa lọ ni wọn sọ pe ki n ṣi oju opo foonu ọhun, ki n maa ba a sọrọ lọ, pe Ọlọrun aa mu un. Awọn agbalagba naa ni wọn lọọ fọrọ ọhun to awọn DSS leti, ko pẹ ti mo ṣoju opo foonu ọhun to fi n ba mi sọrọ pe ki n waa b’oun ni papa isere ‘Fakunle Comprehensive High School’ to wa niluu Oṣogbo. O tun mu mi lọ sinu kilaasi kan, o fi nnkan ọmọkunrin tiẹ han mi, mi o ṣe nnkan kan, ko pẹ ti baba ọdẹ kan to n ṣọ ọgba ileewe naa tun fi kọja, baba ọdẹ yii ko mọ ohun ta a n ṣe lọwọ, oun kan kọja ni tiẹ ni. Loju-ẹsẹ la tuka nibi ta a wa, lẹyin naa lo pe mi lori foonu pe ki n waa ba oun nile to n gbe, ile ẹgbọn rẹ lo pe e fun mi. Nigba ti maa debẹ, o waa ba mi nibi ti mo jokoo si, bẹẹ lo n fọwọ pa mi lara, inu mi ko dun rara, o ni ki n bọ ṣokoto mi, mo bọ ọ, fun gbogbo asiko to fi wa pẹlu mi, mo n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sawọn ọrẹ mi kọọkan lori foonu nipa ohun to n ṣe fun mi. Kooṣi Adebisi fọwọ pa nnkan ọmọkunrin mi, o ri i pe ko le rara gẹgẹ bii ero ọkan rẹ, lo ba fun mi ni foonu tiẹ, fiimu onihooho lo fi n han mi, ero ọkan rẹ ni pe boya ti mo ba wo fiimu onihooho ọhun tan, ara mi aa le e, ṣugbọn lojiji ni awọn ọlọpaa DSS de sile naa, ti wọn fọwọ ofin mu un lọ.
Alukoro ileeṣẹ DSS Dokita Peter Afunaya, fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, pe ọdọ awọn ni Adebisi wa loootọ, tawọn ti n ṣewadii nipa ẹsun ti wọn fi kan an.