Faith Adebọla
Afaimọ ki baale ile ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn kan, Mkwate Chimbizi yii, ma pẹ lẹwọn bii ọbọ, iyẹn bi ọrọ rẹ ko ba ja s’iku latari ẹsun idajọ ọwọ ara-ẹni ati iwa odoro nla to hu siyawo rẹ, Luwiza Leonard, ẹni ọdun mẹtalelogun. Wọn lọkunrin naa fẹsun kan iyawo rẹ pe o n yan ale, o si n fọbẹ ẹyin jẹ oun niṣu, n lo ba fibinu bẹ ẹ lori feu lọjọ tija waye laarin wọn. Lẹyin to pa a tan lo ba tun yọ ọbẹ ti oku ẹ, o rẹ ọmu rẹ mejeeji kuro, o si rẹ abẹ iyawo rẹ ọhun, o sọ wọn si ṣalanga kan, o loun fẹ ko padanu awọn ẹya ara to fi wu ọkunrin mi-in yẹn ni, amọ ọwọ awọn agbofinro ti tẹ ẹ.
Orileede Malawi, nilẹ Afrika wa nibi, lagbegbe Ngabu, to wa niluu Chikwawa, niṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ.
Agbẹnusọ funleeṣẹ ọlọpaa ni ẹka ti Iwọ-Oorun si Ila-Oorun lorileede naa, Edward Kabango, lo ṣalaye nipa iṣẹlẹ buruku ọhun lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa yii. O ni lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, lawọn ti lọọ fi pampẹ ofin gbe afurasi ọdaran naa.
Kabango ni ọjọ kẹta, oṣu Kẹfa, ọdun yii, ni Chimbizi huwa apaayan yii gẹgẹ bi iwadii awọn ṣe fi han. Wọn lo ti pẹ ti gbọnmi-si-i omi-o-to-o ti n waye laarin tọkọ-taya naa, ọkọ yii si lara ẹ maa n gbona sodi, to n jowu buruku, oun lo n figba gbogbo fẹsun kan iyawo rẹ pe alagbere ẹda kan bayii ni, ati pe oju rẹ ko gbe’bikan rara.
Iru ẹsun yii naa lo dija laarin wọn lọjọ buruku ọhun ti baale ile yii fibinu la okuta kan tọwọ ẹ ba mọ iyawo rẹ ọhun lori, niyẹn ba ṣubu lulẹ yakata.
Wọn ni niṣe lọkunrin naa tun fa ada yọ, ada kan ti wọn n pe ni panga, lo ba bẹ iyawo naa lori feu.
Ada yii naa ni wọn lafurasi ọdaran ọhun jẹwọ p’oun fi rẹ ọyan obinrin ọhun mejeeji, oun tun tu iro idi rẹ, oun si rẹ oju-ara ẹ, loun ba lọọ da awọn kinni ọhun nu si ṣalanga ile awọn.
Nigba tilẹ ọjọ naa ṣu ni wọn lo dọgbọn foru boju lọọ sinku iyawo rẹ loun nikan sinu igbo ti ko fi bẹẹ jinna sile wọn ọhun.
Ṣa, awọn ọlọpaa ni afurasi yii ti mu awọn lọ sibi to sin ageku oku iyawo rẹ ọhun si, awọn si gbẹlẹ ibẹ loootọ, awọn ri aabọ ara to sin sibẹ pẹlu ori iyawo rẹ, amọ awọn ẹya ara to ge kuro ko si nibẹ, awọn si ti gbe oku ọhun lọ sileewosan ijọba kan fun ayẹwo.
Wọn lafurasi yii ṣi wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ Malawi, nibi to ti n ṣalaye kikun fun wọn nipa iṣẹlẹ ọhun. Lẹyin iwadii ni wọn lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ.