Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ara o rọ okun, bẹẹ lara o rọ adiyẹ bayii laarin awọn eeyan ilu Ẹrin-Ọṣun ati Ilọba, nijọba ibilẹ Ẹgbẹdọrẹ, nipinlẹ Ọṣun, pẹlu wahala ija aala ilẹ to bẹ silẹ nibẹ lopin ọsẹ to kọja.
Ninu wahala naa, ọkunrin kan tawọn ọlọpaa pe ni Tairu Bidmus gbẹmi mi, bẹẹ ni wọn dana sun ọpọlọpọ ile labule Ilọba.
Wọnlẹwọnlẹ (surveyor) kan la gbọ pe Tairu tẹle lọ sori ilẹ kan ti wahala wa lori ẹ labule Ilọba ti awọn janduku kan ti Saheed Tanfẹani ko sodi fi yinbọn lu u.
Eleyii la gbọ pe o bi awọn kan ninu ti wọn fi bẹrẹ si i dana sun awọn ile to wa ni Ilọba, ti awọn olugbe ibẹ si sa lọ.
Nigba ti Ọlọba ti Ilọba, Ọba Gbadamọsi, n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, o ni ọdọ mẹkaniiki loun wa nigba ti oun gbọ pe awọn janduku kan ya wọnu ibẹ, ti wọn si n dana sun ile.
Ọlọba sọ pe awọn kan ti oun ko mọ ti pa ọkunrin kan ko too di pe awọn ọlọpaa ati ikọ Amọtẹkun debẹ. O ni oun mọ pe nitori ipinnu ijọba ipinlẹ Ọṣun lati sọ oun di ọba onipo-keji lo n da wahala naa silẹ.
O fi kun un pe Timi ti Ẹdẹ lo sọ oun di Ọlọba, ibẹ ni wọn si fi ori baba oun sọlẹ si, ṣugbọn awọn eeyan Ẹrin-Ọṣun ati Ẹgbẹdi n sọ pe oun ko le duro lori ilẹ ti awọn ti n gbe lati aimọye ọdun sẹyin.
O ni oun mọ pe awọn eeyan ilu Ẹrin-Ọṣun ni wọn ran awọn ti wọn dana sun ile ni Ilọba, tori wọn ti kọkọ ba awọn oko wọn jẹ, idi niyẹn to fi rawọ ẹbẹ sijọba lati da si ọrọ naa ko ma baa yọri si itajẹsilẹ.
Ṣugbọn Oloye Abdulfatai Abdulsalam sọ lorukọ awọn eeyan ilu Ẹrin-Ọṣun pe ko si ọmọ ilu naa to dana sun ile kankan niluu Ilọba, bẹẹ ni ko sẹni to ba oko wọn jẹ.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, ASP Yẹmisi Ọpalọla fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, o ni awọn janduku ti Saheed ko sodi lati Ilọba pa ọmọ ilu Ẹrin-Ọṣun kan, Tairu Badmus, lori ilẹ to wa loju-ọna Ẹrin/Ẹgbẹdi.
Ọpalọla ṣalaye pe ọwọ ti tẹ Ibraheem Ọlaniran lori wahala naa, ati pe iwadii n lọ lọwọ.