Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Obinrin kan tawọn eeyan mọ si Titi ni wọn lo pade iku ojiji ti ọpọ dukia si tun ṣegbe lasiko ojo arọọda kan to waye l’Ọba Akoko, nijọba ibilẹ Guusu Iwọ-Oorun Akoko, nirọlẹ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ ta a wa yii.
Ojo nla naa la gbọ pe o bẹrẹ pẹlu iji lile lasiko ti obinrin naa n pada bọ lati inu oko rẹ to wa lagbegbe Ọwa-Odo, lojiji latẹgun si ọpẹ nla kan nidii, to si wo lu obinrin naa mọlẹ nibi to ku si loju ẹsẹ.
Ọpọlọpọ ile, ṣọọbu atawọn ile-ijọsin niluu Ọba ni wọn fara gba ninu ajalu ọhun pẹlu bi iji ṣe ka orule wọn lọ, leyii to ṣokunfa bi omi ojo ṣe raaye ba ọpọ dukia jẹ.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ f’ALAROYE, Ọlọba tilu Ọba Akoko, Ọba Nurudeen Adegoroye, ni ajalu ati ibanujẹ nla lọrọ naa si n jẹ fun awọn araalu.
Ọlọba ni ẹbẹ oun sijọba ati ileesẹ ijọba apapọ to n ri si atunṣe awọn oju ni pe ki wọn tete ran gbogbo awọn to fara gba ninu iṣẹlẹ naa lọwọ nitori pe eyi nikan lo le din ibanujẹ wọn ku.
Ọkan ninu awọn agba ilu to tun fi ẹdun ọkan rẹ han nipa iṣẹlẹ ọhun, Oloye Oloye Tairu Ajana, ni kayeefi lo jẹ fawọn pe iru ojo nla bẹẹ tun le rọ ninu oṣu kọkanla to yẹ ki igba ẹẹrun ti bẹrẹ.
Oloye ọhun ni yoo soro pupọ fun awọn ti iji ba ohun ini wọn jẹ lati tete ṣatunṣe rẹ pẹlu bi ọpọ nnkan ṣe gbowo lori lasiko yii.