Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ajalu mi-in tun waye l’Akungba Akoko, nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii latari ina nla kan to ṣẹ yọ lara awọn ọkọ ajagbe mẹta to fori sọ ara wọn niwaju Fasiti Adekunle Ajasin to wa niluu ọhun.
ALAROYE gbọ lati ẹnu ẹnikan tiṣẹlẹ naa ṣoju rẹ pe ọkan ninu awọn awakọ ọhun to ko simẹnti lo padanu ijanu ọkọ rẹ, to si ṣe bẹẹ lọọ kọ lu awọn ajagbe meji to bajẹ si ẹgbẹ ọna niwaju geeti fasiti naa.
O ni eeyan meji lo ku loju ẹsẹ nigba ti wọn ri ẹnikan gbe de ileewosan ninu awọn mẹta to ha sinu ọkọ ajagbe ọhun.
Ọpọ awọn ẹru to wa ninu awọn ọkọ naa ni wọn lawọn eeyan kan n ji ko nigba ti ina jo awọn mi-in deeru.
Nigba to n fi ẹdun ọkan rẹ han lori iṣẹlẹ naa, Alalẹ tilu Akungba Akoko, Ọba Sunday Ajimọ, ni o digba tijọba ba sọ ọna marosẹ to gba ilu naa kọja di ti onibeji gẹgẹ bii ti Ikarẹ Akoko, ki ijamba ọkọ too dinku lagbegbe ọhun.