Eeyan kan ku, ọpọ fara pa ninu ijamba ọkọ to waye lori biriiji Third-Mainland l’Ekoo

Adewale Adeoye

Ijamba mọto kan waye lori biriji Third-Mainland, to wa niluu Eko, ti ṣokunfa iku ojiji fun gende kan, nigba tawọn mẹjọ mi-in to fara-pa yanna-yanna ninu ijamba naa wa lẹsẹ kan, aye ẹsẹ kan, ọrun nileewosn ijọba ipinlẹ Eko ti wọn ti n gba itọju lọwọ bayii.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, nijamba mọto naa waye laarin awọn mọto akero meji, ṣe ni wọn fori sọ ara wọn nitosi ibudokọ kan to wa lagbegbe Oworonṣoki.

Ọga agba ajọ  to n ri si igbokegbodo ọkọ loju titi nipinlẹ Eko, ‘Lagos State Traffic Management Agency (LASTMA), Ọgbẹni Adebayọ Taofiq, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an yii, sọ pe ere asapaju tawọn dẹrẹba mọto meji naa n sa lo ṣokunfa ijamba ọhun, nitori pe ṣe lawọn mejeeji lọọ fori sọ ara wọn lojiji.

Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘Ijamba mọto kan to waye lagbegbe Oworonṣoki, niluu Eko, lọjọ Aje, Mọnnde, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii, mu ẹmi araalu kan lọ, awọn mẹjọ tun fara pa yannayanna ninu ijamba naa, wọn ti gbe gbogbo awọn ti wọn fara pa ninu ijamba naa lọ sileewosan ijọba kan to wa lagbegbe Gbagada, fun itọju to peye. Mọto akero Mazda, kan ti nọmba rẹ jẹ LND 624 ati mọto kan ti nọmba rẹ jẹ EKY 804 YH, ni wọn fori sọ ara wọn lojiji, ẹni kan ku loju-ẹsẹ, nigba tawọn mẹjọ ṣeṣe.

‘Awọn ọlọpaa Bariga ati Alonge lagbegbe ibi ti ijamba naa ti waye gbiyanju gidi lasiko iṣẹlẹ naa. A ti gbe oku ẹni to ku lọ si mọṣuari ileewosn Gbagada bayii.

Ọga agba ajọ LASTMA waa rọ awọn araalu, paapaa ju lọ awọn dẹrẹba ọkọ ero pe ki wọn yee sare asapajude.

 

Leave a Reply