Eeyan keeyan l’Elisha yii o, ọmọ ọdun mẹrin lo fipa ba lo pọ ni Warewa

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

 

Ọwọ ṣinkun ọlọpaa ti tẹ ọkunrin kan, Elisha James, ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn (25), to gbe ọmọbinrin ọmọ ọdun mẹrin wọ yara, nile wọn to wa ni Warewa, nijọba ibilẹ Ifọ, to si fipa ba a lo pọ gidigidi.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 2021 yii, ni Elisha huwa ọhun. Iya ọmọdebinrin naa ṣalaye fawọn ọlọpaa ni teṣan Warewa pe ni nnkan bii aago meje alẹ ọjọ naa loun bẹrẹ si i gbọ ti ọmọ oun n ke lati inu yara Elisha. O ni boun ṣe wọnu yara naa lọ niyẹn, loun ba ri Elisha to n ba ọmọ oun lo pọ bii agbalagba, to n ki ‘kinni’ ẹ si i labẹ.

Ifisun yii lo mu DPO teṣan naa, CSP Fọlaṣade Tanaruno, ran awọn ọlọpaa lọ sile tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, lopopona Mokore, Warewa, wọn si mu Elisha James to huwa ọdaran naa.

Nigba ti wọn fọrọ wa a lẹnu wo, ọkunrin naa jẹwọ pe loootọ loun ba ọmọ kekere yii sun, toun si ti sọ ọ dobinrin. O ni ṣugbọn oun ko mọ ohun to ko sohun lori toun fi huwa naa.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, sọ pe awọn ti gbe Elisha lọ sẹka to n ri si ṣiṣe

ọmọde yankan-yankan bii eyi, gẹgẹ bi aṣẹ ọga awọn, CP Edward Ajogun, ibẹ ni wọn yoo ti gbe e lọ si kootu fun igbẹjọ.

Leave a Reply